NITORI AYEDERU IWE IRINNA ATI GBAJUẸ, WỌN JU MARY, ỌMỌ ORILẸ-EDE CAMEROON SẸWỌN L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 14, 2019

NITORI AYEDERU IWE IRINNA ATI GBAJUẸ, WỌN JU MARY, ỌMỌ ORILẸ-EDE CAMEROON SẸWỌN L'ABUJA

Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja, eyi to fikalẹ sagbegbe Jabi ti sọ pe iyaale ile oniṣowo kan, Arabinrin Mary Senge pe ko ṣi lọ maa gbatẹgun alaafia latimọle, latari awọn ẹsun oriṣi mẹrin ọtọọtọ ti wọn fi kan an, eyi to nii ṣe pẹlu ayederu iwe igbeluu, lilu jibiti atawọn min in.

Ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC lo wọ Mary lọ sile ẹjọ, niwaju Onidajọ Adebukọla Banjoko, nibi ti wọn ti fẹsun oriṣiriṣi kan an pe pupọ awọn eeyan lo ti lu ni jibiti obitibiti owo, ṣugbọn ti aṣiri ẹ pada tu si wọn lọwọ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun 2018 lo lu ẹnikan ti wọn pe ni John Abila ni jibiti owo ti ko ku diẹ ko pe miliọnu mẹta (2,765,751) naira, pẹlu ẹtanjẹ wi pe o fẹẹ ba aburo rẹ, Lekeaka Gilbert gba fisa lọ si orilẹ-ede Canada, ṣugbọn to na owo naa jẹ.

Ẹsun naa ni wọn loo tun tako ofin ọdaran, abala kinni tọdun 2006, to si ni ijiya labala kẹtala. Ṣugbọn ti Mary loun ko jẹbi pẹlu alaye.

Ṣugbọn ti agbẹjọro ajọ naa, Best Ojukwu sọ pe ko si awijare kankan lẹnu obinrin naa, to si n bẹ ilẹ ẹjọ pe kawọn ṣi fi pamọ sọdọ digba ti yoo gba idajọ to kẹhin.

Bẹẹ ni agbẹjọro obinrin naa, Evi Ofou sọ pe ko si ẹsun ti ko ni idariji, nitori naa, ki ile ẹjọ foju aanu wo o lanu gba beeli ẹ, nitori pe yoo maa wa nigba ti ile ẹjọ ba pe e.

Ile ẹjọ wa a faaye silẹ pe ki wọn gba beeli ẹ ni miliọnu marun un naira, pẹluu oniduro meji ọtọọtọ to wa nitosi kọọtu naa, ṣugbọn ti ko pada ri awọn nnkan ti ile ẹjọ paṣẹ yi mu silẹ, eyi lo fa a ti wọn fi tare ẹ sọgba ẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI