NIBI TI OLE YI TI FẸẸ JI WAYA INA KA LO TI GAN PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 23, 2019

NIBI TI OLE YI TI FẸẸ JI WAYA INA KA LO TI GAN PA

Laarọ onii Sande ni okete gendekunrin kan ti wọn loo fẹran lati maa ji waya ina ka lọọ ta danu ko raaye boru, ati pe orin tawọn araadugbo tiṣẹlẹ naa ti waye n kọ lẹyin iṣẹlẹ naa ni pe 'ọjọ gbogbo ni t'ole, ọjọ kan ni t'olohun'.

Agbegbe Ezinifite nijọba ibilẹ Aguata, ipinlẹ Anambra niṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bi aago meje aarọ onii.

Ohun ta a gbọ ni pe o ti pẹ ti gendekunrin naa ti maa n ji waya ka nidi ẹrọ amunawa (tiransifọma) ti wọn nijọba gbe fun wọn.

Wọn lawọn eeyan ti kilọ fun un pe ko ṣọra rẹ lati maa ba ẹrọ amunawa wọn jẹ latari iwa ole to wa loju ẹ, ṣugbọn ti wọn ni ko gbọ.

Asiko ti wọn loo fẹẹ fọ fẹnsi wọnu ọgba naa ni ina gbe e, to si gan pa loju ẹsẹ. Awọn araadugbo ni wọn sare ranṣẹ sawọn ọlọpaa, ti wọn si gbe oku ẹ lọ si mọṣuari ijọba ti Aguata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI