Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Titi dasiko ti a ṣakojọpọ
iroyin yi tan lọrọ naa ṣi n jẹ kayeefi fawọn
to gbọ,
paapaa awọn
tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja lọ lọhun nigba ti wọn lawọn alaṣẹ ati adari ṣọọṣi Ridiimu, iyẹn The Redeemed Christian Church of God nipinlẹ
Ogun digun lọọ ko awọn ọmọ ijọ naa, to si jẹ pe kaakiri igboro ilu Abẹokuta ni wọnlọọ ja wọn ju si.
Ni nnkan bi aago mejila oru la gbọ
pe awọn
godogodo to wa ninu ile ipagọ naa atawọn ọlọpaa inu Ridiimu naa ko ibọn,
ẹgba,
ti wọn
si lọ
n ko awọn
eeyan naa ti wọn
lọọ ti pe ti wọn ti n gbe inu ile ipagọ naa lai niṣẹ lọwọ wọnu mọto, pe awọn ko fẹẹ ri wọn mọ.
A gbọ pe ko din leeyan igba ti wọn
ko wa sawọn
agbegbe kaakiri iluu Abẹokuta.
Awọn
agbegbe naa ni ikorita NNPC nitosi Oke-Mọsan; Kutọ; Oke-Ṣokori; Ita-Ọṣin atawọn min in, eyi ti wọn
si lawọn
eeyan naa ko mọ
ibi tawọn
wa.
Nigba ti ariwo maa ta, ni nnkan bi aago meje aarọ
tilẹ
ti n mo daadaa, lawọn
araalu bẹrẹ
sii ri awọn
eeyan naa ti wọn
n sunkun lori iwa ti wọn
lawọn
eeyan Ridiimu naa hu si wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ahesọ to kọkọ tẹ AWIKONKO lọwọ tẹle ni pe, ṣe ni ile ipagọ Ridiimu fawọn eeyan naa ṣetutu, ti wọn si lọọ dawọn silẹ kaakiri ọna to jin ki aṣiri ma baa tu, ṣugbọn
nigba ta a de ibi tawọn
eeyan naa wa lagbegbe Oke-Ṣokori, ọtọ ni nnkan ti a ba.
Ẹsẹ
ko gbero nibi tawọn
eeyan naa wa, iyẹn
awọn
ero to waa woran lati mọ
nnkan to n ṣẹlẹ. Ohun to mu kawọn
eeyan maa sọ
oriṣiriṣi
ni bawọn
ti wọn
ja silẹ
naa ko ṣe
tete sọrọ,
ati pe
imura wọn
ko jọ
ti eeyan gidi to mọ
nnkan to n ṣe.
Ṣugbọn
nigba ta a fọrọ
wa wọn
lẹnu wo, ni wọn jẹ ka mọ pe kii ṣe pe wọn fawọn ṣetutu, bẹẹ ni kii ṣe pe wọn lu awọn ki wọn too fagidi ko wọn
wa sibẹ,
ṣugbọn
ṣa,
ojiji to bawọn
lo mu kawọn
fẹẹ le ya were.
Oluwaniṣọla, to jẹ ọkan lara awọn eeyan naa sọ pe “Ọmọ ilu Ikarẹ nipinlẹ Ondo ni mi, ṣugbọn Iwo-Road n’Ibadan ni mo n gbe. Nnkan to ṣẹlẹ ni pe oju lo n dun ọkọ
mi, ti wọn
si ṣiṣẹ abẹ soju naa ni UCH, igba ti wọn
ko ṣiṣẹ abẹ naa daadaa ni wọn
tare wa si ọsibitu tiluu Eko (Eko Hospital), iyẹn
ni nnkan bi ọsẹ
meloo kan sasiko yi.
“Ijẹta tii ṣe Mọnde ni mo gba ile ipagọ Ridiimu lọ
lati lọọ gbadura. Ibi ti mo ti n gbadura niwaju Pẹpẹ
(Alter) ni wọn
ti wa a ba mi lojiji, pe ki n lọ wọ mọto, nigba ti mo si maa mọ
nnkan to n ṣẹlẹ, mo ti ba ara mi nibi yi. Ẹ gba mi o, ko ye mi o. Mi o mọ boya wọn ti kilọ fawọn eeyan tẹlẹ toripe ibẹ kọ ni mo n gbe, bi mo ṣe
wa yii, ko s’owo
kankan lọwọ mi lati pada siluu Ibadan ti mo ti wa.”
Iya ọlọmọ kan toun naa kọ
lati darukọ
ara rẹ
sọ
pe “Ida ọgọrin
ninu ọgọrun
lo jẹ
pe iṣoro
airi ile gbe lo gbe wa de ile ipagọ lati maa gbe, ọmọ
ipinlẹ
Abia ni mi, ṣugbọn
Eko ni mo ngbe, ibẹ
naa ni mo ti ni ipenija ile, idi ti mo fi lọ
sibẹ
niyẹn.
“Mo kọ lẹta si Baba Adeboye fun iranlọwọ,
ṣugbọn
wọn
ko
jẹ
ki lẹta
mi de ọdọ
wọn.
Igba to ya ni mo gbọ
pe wọn
n fawọn
eeyan lowo pe ki wọn
lọọ gba ile, iyẹn loṣu to kọja yi, ṣugbọn mi o ri gba ninu owo naa. Oṣu
kejila ọdun
2018 ni mo ti wa ni Camp, mi o ni mọlẹbi, ọkọ ti mo bimọ ọwọ
mi yi fun ti le mi danu. Iṣẹ awọn to n ṣa katọọnu ni mo n ṣe ni Mowe, ti mo si fi n jẹun
ati ọmọ.
“Ti m ba ṣiṣẹ tan, ni maa lọ su sile ipagọ lọọ sun lalẹ. Wọn maa n sọ lawọn igba kan pe ka kuro nibẹ,
ti wọn
ko ba si wa le wa, a maa duro wa sibẹ, ti wọn ba le wa, ti nnkan ba si lọ
silẹ,
a maa tun pada lọ
sibẹ,
ṣugbọn
eyi ti wọn
ṣe
yi lo buru ju, to si ya wa lẹnu, tori pe ojiji ni, ati pe awọn
ti wọn
wa yẹn
dira wa ni.
“Bọọsi mẹfa lo tẹle ara wọn, wọn ko awọn kan gba ilu Ibadan lọ.
Awọn
Pasitọ
kan ko awọn
eeyan wọn
wa lati wa a ṣe
iṣọ-oru, ti wọn si pinu lati duro fun ipagọ (Congress) ti wọn fẹẹ ṣe lọjọ Fraide ati Satide yi, ti wọn
a si pada ni Sande ana, gbogbo wa ni wọn ko patapata. Ti mo ba ti ri owo ile, maa pada lọ
ko ẹru
mi to wa nibẹ,
mi o si ni debẹ
mọ
ti maa fi ku.
“Wọn kii jẹ ka ri Baba Adeboye, ki aṣiri
wọn
ma baa tu, tori pe owo ti wọn ni ki wọn pin fawọn eeyan, wọn ko pin. Wọn le fun ẹlomin in lẹgbẹrun marun tabi mẹwaa
fun owo ile, ibo leeyan ti fẹẹ ri iru ile towo naa maa gba, wọn
ti ko owo yẹn
jẹ
ni, tori pe ọpọ
igba ni wọn
kii fawọn
eeyan lowo, ki aṣiri
ma si baa tu, wọn
a le awọn
eeyan danu, ṣugbọn
eyi ti wọn
ṣe
gbẹyin
yi lo buru ju. Ko sibi ti mo fẹẹ lọ bi mo ṣe wa yii, tori pe ko ye mi.”
Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ
pe wọn
n gbe ounjẹ
wa fawọn
eeyan naa, ti wọn
si tun fun wọn
lowo diẹ
lati fi kuro lagbegbe naa, pada sibi ti wọn ba fẹẹ lọ.
Ọkan
lara awọn
ọga
ọlọpaa
to wa sibi iṣẹlẹ naa to b’AWIKONKO sọrọ,
ẹni
ta a forukọ
bo laṣiri
sọ
pe ko si nnkan tawọn
fẹẹ ṣe sii, tori pe awọn ko nibi tawọn le ko wọn lọ, dipo bẹẹ, kawọn eeyan naa wa ọna
lati fi lọ
sibi to ba wu wọn.
Sibẹ, ohun ta a gbọ ni pe Baba Adeboye funra rẹ
ko mọ
nnkankan nipa nnkan to ṣẹlẹ yi, tawọn kan si sọ pe ṣe ni wọn fẹẹ fi iwa naa ba orukọ
baba naa jẹ,
bẹẹ lawọn eeyan min in sọ
pe ko yẹ
kawọn
eeyan yi lọọ fi inu ile ipagọ tawọn eeyan ti n gbadura ṣebugbe,
ti wọn
yoo si tun maa ṣe
nnkan to wu wọn
nibẹ.
Nigba to n fesi sawọn ẹsun naa lori foonu, Pasitọ Ọlaitan Olubiyi to jẹ
olori lẹka
eto iroyin ni ile ipagọ naa jẹ ko ye wa pe awawi lasan lawọn
eeyan naa n wi, tori pe ọpọ igba lawọn ti le wọn kuro ṣugbọn ti wọn ko lọ.
Olubiyi ni, ọna lati dẹkun awọn iwa ibajẹ bii ole jija, ọbun
atawọn min in lo fa igbesẹ naa, tori pe pupọ
awọn
alainiṣẹ lọwọ atawọn ti wọn ko nile lori lo n fi inu ọgba
naa, paapaa awọn
ṣọọṣi ibẹ ṣebugbe, tawọn min in si tun n jale.
Bẹẹ lo sọ pe bawọn ṣe n fun awọn ti wọn ko nile lori lowo ile ni wọn
tun n pada wa, ati pe bawọn eeyan ba iranlọwọ
wa, lẹsẹkẹsẹ
lawọn
n ṣe e fun wọn lati ma gba iwa ọdaran
laaye. Bakan naa lo lawọn ṣakiyesi pe wọn ti sọ iwa naa di iṣẹ, eyi to si n ta abuku ba wọn.
No comments:
Post a Comment