Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi ni ko tii sẹni to le sọ ibi ti ọrọ iyaale ile kan, Fatima yoo ja si, latari bi wọn loo ṣe gun ọkọ rẹ ti wọn ṣegbeyawo papọ loṣu mẹfa sẹyin ni ọbẹ makanjẹ latari aawọ kekere kan ti wọn loo bẹ silẹ laarin wọn.
AWIKONKO rii gbọ pe ni kete ti tọkọ-tiyawo naa ti ṣegbeyawo, ni wọn lọkọ ti maa n luu Fatima, ko da a ti wọn sọ pe aludaku lo ma n fi iyawo ẹ ṣe.
Ati ẹ gbọ pe ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni ọkunrin naa lu Fatima, to si mu ki oyun oṣu mẹrin to wa lara ẹ jabọ silẹ, to jẹ pe lẹyin ọsẹ meji lo too gbadun ara rẹ diẹ.
Ọkọ naa ṣi wa nibi to ti n gba itọju lọwọ bayii, bẹẹ ni Fatima ti wa lagọ ọlọpaa, nibi to ti n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe oun fi ọbẹ naa gba ara oun kuro lọwọ ọkọ oun ni, tori pe ojoojumọ lo maa n lu oun lalubami.
No comments:
Post a Comment