Lọjọ Tọside ijẹta ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun kede gbajugbaja oniroyin, Ọgbẹni Sunday Ọlankunle Ṣomọrin gẹgẹ bi akọwe iroyin ti yoo ba a ṣiṣẹ pọ ninu ijọba ẹ.
Bo tilẹ jẹ pe o ti to bi ọjọ meloo kan tawọn araalu ti n beere pe igba wo ni Gomina tuntun naa yoo bẹrẹ sii kede awọn alabaṣiṣẹpọ ẹ, ṣugbọn to jẹ pe akọwe iroyin yi lo fi bẹrẹ lọjọ Tọside.
Ọpọ ileeṣẹ iroyin ni Ọgbẹni Sunday Ọlakule ti ṣiṣẹ, to si tun ni imọ ijinlẹ iwe ninu iṣẹ iroyin to yan laayo.
AWIKONKO n fi asiko yi ki ọkunrin naa ku oriire, ta a si gbadura pe yoo ṣe aṣeyọri nidi iṣẹ to gba naa.
No comments:
Post a Comment