Bo tilẹ jẹ pe a ko tii gbọ boya ọwọ ọlọpaa ti tẹ iyaale ile kan ti wọn loo gun ọkọ rẹ ti wọn ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo alarinrin laipẹ yi ni abẹrẹ to jẹ pe oogun ti wọn fi n pa ekute lo rọ sinu ẹ, sibẹ epe rabandẹ-rabandẹ lawọn to gbọ siṣẹlẹ naa n gbe obinrin naa ṣẹ titi di asiko yi.
Iluu Jos niṣẹlẹ aburu naa ti waye nigba ti wọn sọ pe awọn ọrẹ iyawo tuntun naa ni wọn gba a nimọnran pe ko fi ọkọ rẹ to ṣẹṣẹ fẹ naa silẹ, tori pe awọn ti baa ri baba olowo nla kan ti yoo maa tọju ẹ daadaa siluu Abuja.
Wọn ni ki aṣiri ma ba a tu pe obinrin naa lo pa ọkọ ẹ, lo ba gbiyanju lati ra abẹrẹ, to si tun lọọ ra oogun ekute, eyi ti wọn loo gun ọkọ ẹ lasiko to wa loju oorun, to si ko ẹru rẹ salọ.
Ọsibitu ijọba tawọn olukọni, iyẹn Teaching hospital to wa niluu Jos ni ọkọ-iyawo naa wa bayii, to n gba itọju lọwọ.
No comments:
Post a Comment