Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yi,Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe kawọn to n tẹlẹ awọn ọrọ Aarẹ Buhari ma sọ ara wọn nu sinu ẹtanjẹ nitori pe oko iparun ni Aarẹ Buhari n wa ọkọ orilẹ-ede Naijiria lọ nitori pe gbogbo igbesẹ ti Aarẹ n gbe, ipasẹ iparun lo n tọ.
Nibi ifọrọwerọ pẹluu akọroyin kan laipẹ yi ni Oloye Ọbasanjọ ti sọrọ naa, to si jẹ ko di mimọ pe eto ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria ti dẹnu kọlẹ labẹ
isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, ati pe awọn to n tẹle e ko le ba a sọrọ.
Oloye Ọbasanjọ tẹsiwaju pe nipa ti igbogun ti iwa ajẹbanu ti Aarẹ Buhari n pariwo pe oun n gbogunti, o ni ẹtanjẹ lasan lo wa nibẹ nitori pe awọn oloṣelu to wa lẹgbẹ alatako lasan ni Aarẹ Buhari n gbe, ti wọn ko gbe awọn oniwa ibajẹ tẹgbẹ oṣelu APC toun funra rẹ wa.
O wa fi kun ọrọ rẹ pe ni saa ẹlẹẹkeji ti Aareẹ Buhari n lo lọ yi, ko0 daju pe eto ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria yoo lọ soke ju bo ṣe yẹ lọ, ati pe bi ko ba ja wa silẹ, yoo duro soju kan lasan ni.
No comments:
Post a Comment