Láti ọwọ ọ - JỌLÁADÉ ADÉLAKÙN
Olówó ayé o se mèdò.
Mèkúnù ayé sóra re.
Kòlòkòlò kan nilé ayé tí n gbéni mì lááyè.
Báyé bán lo, won a ní ó n yí bí aago.
Báyé bá n sáré títí, n padè bòwá.
Sé owó loní tí gànran- gànràn ré wà pò.
Sé ipò gíga lo wà, tí o wá n sapá yanga-yanga.
Òpó gbonranran tí o wà lókè re yii, rántí pé èèyàn
lo fi s'àtègùn e.
A kìí súré títí ká kojá ilé.
A kìí rìn gbèrè ká sùn lébá ònà.
Ohun a fèsò mú kìí bàjé, ohun a f'agbára mú, kokoko
báyíi ní n le!
B'áyé bá ye ó, má se dunnú jù.
Torí olówó ànà kúrò l'éni a n fò kúrò l'éyìnkùlé
fún.
Òpò alàgbára lóti subú.
Òpò akínkanjú lóti wolè lááyè.
No comments:
Post a Comment