IJA PARI: DANGOTE ATI FAYẸMI PARI IJA LAARIN GANDUJE ATI ẸMIR ṢANUSI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 9, 2019

IJA PARI: DANGOTE ATI FAYẸMI PARI IJA LAARIN GANDUJE ATI ẸMIR ṢANUSI

Ganduje and Sanusi 
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Abdullahi Ganduje ki Emir ilú Kano Muhammedu Sanusi ní ìlú Abuja ní ọjọ Jimọ lásìkò ti wọn fẹ yanju ààwọ to wà láàrin wọn.

Gẹ́gẹ́ bí àgbẹnusọ fún gọ́mìnà Abbaa Anwar ṣe sọ gbájúgbaja ọmọ bibi Kano àti alága àwọn gomina Nàìjíríà Kayode Fayemi ló pe ìpàdé ti wọ́n fi pẹ̀tù sí ààwọ̀ àwọn méèjì.

Awọn adari méèjì sare papọ bí wọn ṣe rọ àwọn musulumi láti túbọ máa[tèlé àwọn ẹ̀kọ́ ti wọn kọ ninu ààwẹ Ramadan, bákan náà ni Emir fi asìkò náà kí gómìnà kú ori ire ìwọle fún sáà keji.

Láti ìgbà díẹ̀ sẹyin ni ààrin Gomina ipinlẹ Kano Ganduje àti gómìnà ilé ifowopamọ apapọ tẹ́lẹ̀ri Sanusi Lamido Sanusi kò ti gún. ìròyìn sọ pé àì gbáruku ti ìjọba Ganduje ni inú ìdìbò tó koja ló fàá.

Èyí ló fa gbọ́nmisi-omi o to lẹ̀yìn ti ìdìbò pari ti gómínà Ganduje si wolé fún sáà keji, Gomina Ganduje buwọ lu abádofin láti ṣe ìdásilẹ̀ àwọn ààfin tuntun míràn ni Gaya, Rano àti Karaye ti wọn ó si jọ ni agbára àti àṣẹ kan náà bi ti Emir Kano gẹ́gk bi ọba onipo kíní

Ní ọjọ́bọ ni ìjọba tún fi ìwé wá wi tẹnu rẹ ránsẹ si Emir Sanusi láti sàlàye bí ọ ṣe ná bílíoọnù mẹ́ta o lé ọwọ́ mẹ́rìn ti Emir ṣe mọ́umọ̀ku

Olubadamọran gómìnà Saliu Tanko sọ fún BBC pé ìpàdé láti pẹtu sí ààwọ náà ló wáye fún ìgbà aàkọkọ ní alẹ́ ọjọ Jimọ

Emir Sanusi kìí ṣe akápò tàbí akọ̀wé ìgbìmọ ẹ́míréètì- Abba Yusuf àgbẹnusọ Emir Kano

Emir Kano Muhammedu Sanusi II tí fèsì sí ìwé ẹ̀sùn ti Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano kọ síi ni ọjọ́ pé kó wá wi tẹ́nu rẹ̀ lóri bí ó ṣe na bílíọ̀nu mẹ́ta lé ọwọ́ mẹ́rin náírà owó igbìmọ ẹmireeetì.

Gẹ́gẹ́ bii ǹkan ti Abba Yusuf sọ, ó ni ọwọ́ Emir kò le wọ sọ̀ọ̀lọ̀ nítori pe kìí ṣe akápò tàbí akọwé fún ìgbìmọ ẹmireeti.

Yusuf fi kun pe wọn yan Sanusi gẹ́gk bi Emir ni ọdún 2014, owó ti ó wà ni àpò ẹmireeti ko ju bílíọnu kan lé díẹ̀ l, èyí jìnì gédégédé si bílíọnu mẹta lé ọwọ mẹ́rìn tí àwọn ajọ to gbógun ti ṣ\iṣe owó ìlú makumọ̀ku ń sọ pe Emir na láàrin ọdún 2014 si 2017 lọ.

Ní ọjọ́ru ni àjọ tó ń ri si iwa àjẹbanu ni ìpínlẹ̀ Kano dábàá pe ki wọn yọ Sanusi nipò nítori ó ṣe owo ìgbìmọ ẹmireeti niṣekuṣe.

Àbá yìí wà nínú àbájade ìwádìí ti àjọ náà ṣe ti àlága wọn Muhuyi Magaji si fọ́wọ́ si.

Ẹ̀wẹ̀, akọwé ìjọba ìpínlẹ̀ Kano tó kọ ìwé ẹsun náà Usman Alhaji sàlàye pe èsì Sanusi yoo fún ìjọba láàfàní láti gbé ìgbésẹ̀ to tọ àti èyí to yẹ.

BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI