IGBEYAWO: ẸNI BI ỌKAN YIN NI KI Ẹ TẸLE LỌ - IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN GBAWỌN ỌDỌ LAMỌNRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 1, 2019

IGBEYAWO: ẸNI BI ỌKAN YIN NI KI Ẹ TẸLE LỌ - IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN GBAWỌN ỌDỌ LAMỌNRAN

Oluwaṣeun Boye

Ẹsẹ ko gba ero ni ṣọọṣi Chapel of Christ the Light to wa lagbegbe Alausa, Ikẹja niluu Ekoo lonii, nibi ti Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo ti ṣe igbeyawo fun ọkan lara awọn ọmọ ẹ, Adedamọla Bọdunrin Tẹjuoṣo.

Nibẹ ni Igbakeji-Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti gbawọn ọdọ, paapaa awọn ti wọn ti kun oju oṣuwọn lati ṣegbeyawo lamọnran pe ẹni ti wọn ba nigbagbọ ninu ẹ, ti wọn si ri ẹni naa gẹgẹ bi ẹni bi ọkan wọn ni ki wọn ba so yigi papọ, nitori pe igbeyawo kii ṣe adehun ọlọjọ, bi ko ṣe titi lai.
 
Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele jẹ ko di mimọ pe igbeyawo gba suuru to pọ, nitori naa lawọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ṣe gbọdọ farabalẹ nipa wiwa ololufẹ ti wọn yoo jọ gbe titi lai.

Bakan naa lo tun sọ pe ololufẹ meji gbọdọ mọ iwa ara wọn daradara ki wọn too pinu lati ṣegbeyawo, ki wọn ma baa sare jade ninu igbeyawo naa.

Bẹẹ lo bawọn tọkọ-taya tuntun naa ṣajọyọ, to si ki wọn ku oriire to wọle tọ wọn.

Ṣaaju asiko yi, Oniwaasu ayẹyẹ naa, Biṣọọbu ijọ Adulawọ ti Ẹkun Ẹgba, Peter Oyero ninu iwaasu ẹ to yọ latinu ẹsẹ bibeeli Efesu 5:21 lo ti gbawọn tọkọ-tiyawo maa lamọnran pe ki wọn maa bọwọ fun ara wọn, ati pe ọkọ ni olowo ori iyawo ẹ, to si laṣẹ lati pa nigbakugba.

Bẹẹ lo tun jẹ ko ye wọn pe wọn gbọdọ jẹ ki iwa laaye ọlọrun jọba ninu idile wọn, paapaa ki wọn gba Jesu Kristi gẹgẹ bi olori ile wọn lati le jẹ ki igbeyawo lọ kọnrinkese, to si tun rọ iyawo tuntun naa pe ko maa bọwọ fun ọkọ ẹ, ko si tun maa ran ọkọ ẹ lọwọ ninu adura, owo ati ni gbogbo ẹka to ba nilo iranlọwọ ẹ.

Lara awọn to tun wa nibi igbeyawo naa ni; Jẹnẹra Ọladipupọ Diya, adajọ agba nipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu; iyawo Aarẹ orileede yi tẹlẹ Arabinrin Bọla Ọbasanjọ; Iyalode ilẹ Yoruba, Oloye Alaba Lawson, Senetọ Lanre Tẹjuoṣo atawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI