IGBESẸ LATI BẸRẸ ETO ILERA TO PEYE BẸRẸ NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 20, 2019

IGBESẸ LATI BẸRẸ ETO ILERA TO PEYE BẸRẸ NIPINLẸ OGUN

Oluwaṣeun Boye

Lati le mu awọn ileri tijọba ipinlẹ Ogun ṣe lasiko ipolongo idibo, paapaa lẹka eto ilera ṣẹ, ijọba ti sọ pe igbesẹ lati bẹrẹ atunṣe gbogbo awọn ọsibitu kekeeke ati nla kaakiri ipinlẹ naa ṣe, kawọn araalu le tubọ jẹgbadun eto ilera to peye.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele lo fidi ọrọ naa mulẹ laipẹ yi, to si tun jẹ ko di mimọ pe ijọba ti ṣetan lati kọ awọn ile iwosan min in si kaakiri awọn igberiko patapata.

Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele lo jẹ ko di mimọ lasiko to gba awọn eleto aabo ilera kan, National Association of Government General Medical and Dental Practitioners, (NAGGMDP), ẹka tipinlẹ Ogun  lalejo ninu ofiiisi ẹ to wa no Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.

Nigba to n kanminu lori ipo tawọn ọsibitu kaakiri ipinlẹ naa wa, eto ilera lo yẹ ko jẹ pataki sijọba, ati pe ko gbọdọ jẹ nnkan ti wọn nfi ọwọ yẹpẹrẹ mu, ṣugbọn awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ipadabọsipo ba gbogbo ọsibitu patapata.

Obinrin naa sọ pe loju ẹsẹ tawọn ti ri awọn nnkan wọnyii lawọn ti yan igbimọ ti yoo ṣewadi awọn nnkan wọnyi, tori naa lo ṣe jẹ pe abajade igbimọ naa lawọn reti.

Ṣaaju asiko yi ni alaga ẹgbẹ naa, Dọkitọ Olufẹmi Odulatẹ nigba to n ki igbakeji Gomina ku oriire, paapaa ijọba ipinlẹ Ogun, o sọ pe awọn ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹluu ijọba lori ọrọ ilera.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI