Bi ẹ ṣe n ka iroyin ni gbogbo
awọn eeyan patapata kaakiri aggbaye, paapaa lorilẹ-ede Naijiria ni wọn n fi
atẹjiṣẹ oriṣiriṣi ranṣẹ si ọkan pataki lara awọn ilu mọn ọn ka sọrọsọrọ nni, Ibrahim
Kẹhinde Iṣọla tawọn eeyan mọ si Van Garuba lati fi kii ku ayẹyẹ ọjọ to n ṣe
lonii, ogunjọ oṣu kẹfa.
Odu ni Van Garuba, kii ṣaimọ
foloko lagboole pedepede lorilẹ-ede Naijiria, paapaa nipinlẹ Ogun to fi
ṣebugbe, to si jẹ pe ọkan pataki lara awọn pedepede to ṣẹṣẹ n dide bọ nidi iṣẹ
naa ni.
Ko sẹni to gbọ lara awọn eto ẹ
to maa n ṣe lawọn ori redio nipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Ọyọ ti wọn kii gbe oṣuba
kare fun un, idi ni yii tawọn olugbọ redio fi n kan saara sii pe ọkin jọba
laarin awọn ẹyẹ.
Adẹrinpoṣoonu Ọmọ bibi ilu Ilọrin to dagba
sipinlẹ Ọyọ naa lo jẹ pe pupọ awọn agba nidi iṣẹ naa ni wọn maa n fẹ baa ṣe pọ
latari awọn agbekalẹ ẹ ti ko ni aṣaaju to fi n ṣeto kaakiri ile-iṣẹ redio.
Bo ṣe gbajumọ laarin awọn ẹgbẹ
sọrṣorṣo naa lo tun jẹ odu laarin ẹgbẹ oni tiata atawọn olorin patapata.
Lati ana tii ṣe Wẹside la gbọ
pe awọn ololufẹ ẹ ti n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sii, ko da a ta a tun gbọ pe ṣe lawọn
eeyan n fi owo taaka laarin ara wọn lati kọkọ mọ ẹni ti yoo kii lonii fun ọjọ
ibi naa.
Bi ẹ ba ṣi redio yin bayii, o
fẹẹ le jẹ pe ko si ile-iṣẹ redio kan ṣoṣo ti wọn ko ti nii kii ku oriire ọjọ
ibi ẹ, tori pe latigba ti aago mejila aarọ oni ti lu lawọn ile-iṣẹ redio ti n
kii, ko da ti wọn tun gbe orin tawọn kan fi mọ riri ẹ sori afẹfẹ.
Ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL
to n gbe Iroyin Awikonko jade sita naa wa n lo asiko yi lati fi mọ riri ipa ti
ọkunrin naa n ko lori ile-iṣẹ wa, tori pe ọkan pataki lara awọn to n gbe
ile-iṣẹ wa larugẹ ni Van Garuba jẹ.
Aṣeyiṣamọdun, ti a si n gba a
ladura pe igbega ni yoo ma a jẹ ti ẹ ni gbogbo ọjọ aye ẹ. Ẹni to ba ri Van
Garuba, ko ba wa kii daadaa pe ‘igba ọdun, iṣẹju aaya kan ni fun un’.
No comments:
Post a Comment