GBAJUMỌ OṢERE TIATA KU SINU OMI L'OTẸẸLI TO TI LỌỌ ṢE FAAJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 26, 2019

GBAJUMỌ OṢERE TIATA KU SINU OMI L'OTẸẸLI TO TI LỌỌ ṢE FAAJI

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Gbogbo agboole amuludun patapata lorilẹ-ede Naijiria ni wọn tun ti wa ninu ọfọ bayii latari bi wọn ṣe padanu ọkan lara wọn to jẹ gbajugbaja oludari ere ati oṣere, Kagho Harley Akpọr, ẹni ti wọn loo ku sinu omi lasiko to n wẹ lọwọ ni otẹẹli kan to wa niluu Asaba, ipinlẹ Dẹlta.

Bọ tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi ẹ mulẹ daadaa lori bo ṣe ku sinu omi latari ahesọ to n lọ kaakiri igboro.

Bawọn kan ṣe n sọ pe ibi ti wọn ti n ya fiimu tuntun ti wọn fẹ ẹ gbe jade ni oṣere tiata naa jabọ sinu agba omi (pool) yi, to si jẹ pe nigba ti wọn maa yọ jade, ẹlẹmin ti gba a, Bẹẹ lawọn kan sọ pe faaji ni ọkunrin naa lọọ ṣe ni otẹẹli yi, to si jẹ pe iamọọwẹ lo jẹ ko kagbako iku ojiji yi.

Ṣugbọn kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Dẹlta, Ọgbẹni Adeleke Adeyinka nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni nnkan tawọn eeyan n sọ yatọ patapata si ohun to ṣẹlẹ gangan, ṣugbọn toun ko nii sọ nnkan to ṣẹlẹ gan an ni pato.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI