Ere lawọn eeyan kọkọ pe e, to si tun pawọn to wa nibẹ, atawọn to gbọ lẹrin in nigbga ti Arabinrin Aishat Buhari to jẹ iyawọ Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe oun ko ni i fẹ kawọn eeyan maa pe oun ni 'Iyawo Aarẹ' lati asiko yi mọ.
O ni 'Obinrin Akọkọ' loun fẹ ki wọn maa pe oun lati asikọ yi lọ, nitori pe iyalẹnu lo maa jẹ foun nigba ti wọn ba a pe awọn orukọ awọn iyawo Gomina, ti wọn si n pe Obinrin akọkọ, ṣugbọn to jẹ pe iyawo Aarẹ ni wọn n pe oun.
Nibi eto aami ẹyẹ kan to waye ninu gbọgan ayẹyẹ to wa nile-iṣẹ Aarẹ, iyẹn Banquet Hall, nibi to ti fawọn iyawo Gomina tẹlẹri, atawọn to nipo lorilẹ-ede yi laami ẹyẹ lo ti sọrọ naa.
No comments:
Post a Comment