Ṣàǹgbà fọ́ lánàá nígbà tí Andy Ruiz ọmọ Ilẹ̀ Mexico
fi ẹ̀ṣẹ́ àràmàǹdà kan fọ́ kèrékèré Anthony Joshua níbi ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn tó wáyé
ní Madison Square Garden ni USA.
Ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ruiz fi ẹ̀ṣẹ́ dá Ọ̀gbẹ́ni
náà dọ̀bálẹ̀ tí kò sì rí nǹkan ṣe síi. Ń ṣe ló dà bí pé ẹ̀ṣẹ́ Ruiz ń kọ́
Anthony Joshua lóòyì. Èyí ló fà á tí àwọn kan fi sọ wípé bóyá ni kìí ṣe àwọn
ará Abúlé rẹ̀ ní Ṣagamu ló gba àbòdè fún-un. Wọn ní nígbà tí òun náà kò wálé
láti wá gba àjẹsára.
Ṣùgbọ́n àwọn kan tún sọ pé Jóṣúà mọ̀ọ́mọ̀ fi ara rẹ̀
sílẹ̀ ni, àti pé eléyìí yíò mú kí owó ńlá bọ́ sí ọwọ́ rẹ̀ nígbà tí wọn bá fẹ́ẹ́
tún ìjà náà jà. Mọ̀jà mọ̀sá làá mọ akíkanjú l'ógun.
- Ìròyìn Àdíndùn
No comments:
Post a Comment