Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Bi
iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ
pe afi ki gbogbo ile-iṣẹ eleto aabo patapata nipinlẹ Ogun mura lati doola ẹmi ati
dukia awọn araalu, paapaa gbogbo Banki to wa niluu Ṣagamu.
Ati pe titi di asiko ti a fi ko iroyin yi jọ ni gbogbo awọn araalu ati olugbe ilu Ṣagamu fi wa ninu ibẹrubojo lori bawọn banki ṣe ti ilẹkun wọn pa lori iroyin to ti gba igboro kan yi.
Ohun ta a gbọ ni pe wọn lawon ogbologbo adigunjale kan ti ko tii sẹni to mọ wọn dasiko
ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan ṣe kọ lẹta sawọn banki meloo kan pe ki wọn maa mura
silẹ, nitori pe awọn n bọ lati wa a gba ẹtọ wọn kuro lọwọ wọn.
Ọsẹ
to lọ lọhun la gbọ pe awọn Banki kan ti wọn wa loju ọna Sabo niluu Ṣagamu gba awọn lẹta naa, to si mu wọn ko sinu wahala pe nibo lawọn fẹ ẹ
gba pẹlu owo olowo ti wọn n tọju.
Loju ẹsẹ ti wọn ni lẹta naa ti tẹ wọn lọwọ ni wọn ti tawọn ọlọpaa lolobo,
paapaa Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Baṣhir Makama, ti wọn si ni Kọmiṣana
funra rẹ ti sọ fun gbogbo awọn Banki to wa nibẹ pe ki wọn ṣi ti ilẹkun
wọn fungba diẹ naa.
Ọjọ
Mọnde ọsẹ to kọja yi la gbọ pe gbogbo Banki to wa niluu Ṣagamu patapata
ti tilẹkun wọn pa, ti wọn ko si tii ṣilẹkun titi di onii Wẹside.
Bo
tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi ẹ mulẹ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ṣugbọn ahesọ to ta si wa leti je ko ye wa pe awọn adigunjale naa
kii ṣe ipinlẹ Ogun ni wọn wa, ati pe kaakiri orilẹ-ede Naijiria ti wọn
lawọn eeyan si ni wọn ti ko ara wọn jọ, ta a si gbọ pe iluu Benin nipinlẹ Ẹdo ni wọn fi ṣe olu-ile-iṣẹ wọn, ti won si lawọn adigunjale naa tọpinpin
lori ọna ti wọn fẹ ẹ gbe iṣẹ naa gba tọsan toru.
Ere
la kọkọ pe e nigba tọrọ naa tẹ wa leti lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi, ṣugbọn nigba ta a de bẹ lopin ọsẹ to kọja yi la ṣakiyesi pe ilu
Abẹokuta ati Ijẹbu-Ode lawọn to ba fẹ ẹ gba owo ti lọ n gba owo bi wọn ba
nilo owo.
AWINKONKO gbọ pe ikọ ọtẹlẹmuyẹ gan an ti bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ lati maa ṣewadi tọsan toru awọn ọdaran naa.
Lati
fidi iroyin naa mulẹ, AWIKONKO gbiyanju lati ba alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lo ja si pabo, bakan naa la ko ri Ọgbẹni Silas to jẹ
igbakeji rẹ naa sọrọ ta a fi ṣakojọpọ iroyin yi tan.
Ohun
tawọn kan ti ẹ sọ ni pe o ti le lọdun mẹjọ tiru nnkan bayii ti ṣẹlẹ,
eyi to mu ki wọn rawọ ẹbẹ sijọba Dapọ Abiọdun pe ko ma ṣe fi ọrọ eto
aabo ṣere rara, nitori nnkan ti wọn fi jẹgbadun ijọba to kọja ju ni eto
aabo to peye to wa fawọn araalu.
No comments:
Post a Comment