EEMỌ WỌLUU O: WON NI INAKI GBE MILIỌNU MEJE NAIRA MIN-IN NI KANO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 14, 2019

EEMỌ WỌLUU O: WON NI INAKI GBE MILIỌNU MEJE NAIRA MIN-IN NI KANO


Titi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lọrọ naa ṣi n ṣe awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn eeyan kaakiri agbaye ni kayeefi lori bi wọn ṣe fẹsun kan ọkan lara awọn ẹranko kan ti wọn pe ni Inọki ṣe gbe owo to fi diẹ din ni miliọnu meje (6.8) naira min in.

Ile-iṣẹ irin ajo afẹ kan ti wọn ti n wo awọn ẹranko nipinlẹ Kano, iyẹn Kano Zoological Gardens (tourist centre) la gbọ pe iṣẹlẹ abami naa ti waye gẹgẹ bi iroyin to tẹ walọwọ ṣe fidi ẹ mulẹ.

Akọwe owo ọgba naa lo fidi ẹ mulẹ pe ṣe ni Inọki (Gorila) naa yọ kẹlẹkẹlẹ kuro nibi ti ọn fi pamọ si, to si ra kooro wọnu ọfiisi ti wọn gbe owo pamọ sii, to si ko o salọ lati lọọ bẹrẹ sii ko o owo naa jẹ.
 
A gbọ pe asiko ayẹyẹ ọdun itunnu aawẹ to kọja yi niṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn ti wọn ko tete fura, ṣugbọn nigba ti wọn maa mọ nnkan to n ṣẹlẹ, owọn loo ti ya owo mọ igbẹ danu.

Alakoso ọgba awọn ẹranko yii, Ọgbẹni Umar Kobo fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹ, lati mọ ọna abayọ.
 
Ninu ọrọ rẹ, Kobo sọ pe "A ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa, mi o si tii fẹẹ sọ nnkan nipa ẹ lasiko yii. Ọpọ awọn akọroyin ni wọn ti wa a lati ṣewadii, ṣugbọn ti mi o da wọn lohun. Nnka ti mo le fidi ẹ mulẹ fun un yin bayii ni pe owo sọnu lootọ."

AWIKONKO gbọ pe awọn mẹwaa ninu awọn oṣiṣẹ ọgba naa, iyẹn awọn ti wọn wa lẹnu iṣẹ nigba ti owo naa sọnu ni wọn ti wa latimọle ọlọpaa bayii, ti wọn fọrọ wa wọn lẹnu wo titi dasiko yi.

Ohun tawọn eeyan n sọ bayii ni pe awọn ko tii gbagbọ, ati pe to ba ri bẹẹ, afaimọ ko ma jẹ awọn yoo bẹrẹ sii lu awọn ẹranko pa, paapaa awọn ẹranko to ba layika ile ifowopamọ sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI