Ẹ WOJU SỌDIQ TO N FI ỌKADA JALE N'IKORODU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 3, 2019

Ẹ WOJU SỌDIQ TO N FI ỌKADA JALE N'IKORODU O

Ọlaide Ọṣinuga, Eko


Orin, ilu ati ijo lawọn araalu Ikorodu gbe lonii, ti wọn n dupẹ kaakiri ilu naa, nigba tọwọ palaba gbajumọ adigunjale kan, Rasak Sọdiq segi.

A gbọ pe ọkada ni Sọdiq fi maa n jale kaakiri, taṣiri ẹ si tu lopopona Ijede, Ikorodu.

Awọn to fiṣẹlẹ naa to AWIKONKO leti laipẹ yi jẹ ko ye wa pe ki i ṣe Sọdiq nikan lo n fi ọkada yi jale, o lawọn amugbalẹgbẹ ti wọn jọ wa nidi iṣẹ naa, tawọn si ni ba ẹsẹ wọn sọrọ ni kete ti akara tu sepo.

Teṣan ọlọpaa SARS ni Sọdiq wa bayii to ti n bẹbẹ pe ogun idile lo n ti oun lọọ jale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI