Bi ẹ ṣe
n ka iroyin yi, ọgba SARS to wa ni Magbọn niluu Abẹokuta ni gendekunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan, Oluwaṣeun Fakoyejọ wa to n bẹbẹ fun idariji latari bi
wọn ṣe muu lọjọ Wẹside to kọja yi, lasiko ti wọn loun atawọn ẹmẹwa ẹ tawọn ti na
papa bora da wahala silẹ nibi eto ibura ti wọn ṣe fun Gomina tuntun nipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun.
Ohun ta
a gbọ ni pe ko too to asiko yi lawọn ọlọpaa ti gbọ pe awọn kan n gbero lati da
wahala silẹ nibi eto naa, ti wọn si lawọn ọlọpaa naa ti gbaradi fun wọn
lati fi ẹnikẹni tọwọ palaba ẹ ba segi jofin.
A gbọ
pe bi eto naa ṣe n lọ lọwọ ni wọn lawọn kan ti n dọgbọn fẹhonu han, ṣugbọn to
jẹ pe awọn ọlọpaa, sifu difensi atawọn fijilante ni wọn n da wọn lọwọ kọ, ko si
pẹ ti wọn pari eto naa la gbọ pe wahala nla naa bẹrẹ ni pẹrẹu, tọrọ si di boolọ
o yago.
Iroyin
to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe bi Gomina Abiọdun atawọn alejo ṣe lọ
tan ni Ṣeun atawọn yooku ẹ ti bẹrẹ sii lu awọn eeyan, ti wọn si n fi awọn nnkan
ija oloro halẹ mọ awọn eeyan lọjọ naa.
Lẹsẹkẹsẹ
ni wọn lawọn kan ti ta awọn SARS lolobo, tawọn yẹn si sare de ibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn
to jẹ pe bi wọn ṣe foju gan-an-ni awọn SARS ni wọn ti bẹrẹ sii ba ẹsẹ wọn sọrọ
lẹyọkọọkan.
A ti ẹ
gbọ pe wọn gbẹmi eeyan kan si Papa iṣere MKO to wa ni Kutọ nibi ti eto naa ti
waye, ṣugbọn ti a ko pada ri okodoro dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
Wọn ni
lasiko ti Ṣeun n salọ ni wọn rọwọ too, ti wọn si ka ibọn ilewọ kekere kan mọ ọn lọwọ. Eyi gan nan ni wọn lo gbe de teṣan ọlọpaa to wa ni Magbọn, nibi to ti n
gbaradi lati foju bale ẹjọ.
Agbẹnusọ
fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe lootọ lọwọ
tẹ Ṣeun, ti ọga wọn, Bashir Makama si ti paṣẹ pe wọn gbọdọ ṣe iwadii kikun lori ọdaran naa, ki wọn si rọwọ to awọn yooku ti wọn salọ, ki wọn too fẹsẹ ofin mu
wọn.
No comments:
Post a Comment