Diẹ lo ku ki wọn lu ọmọdebinrin kan pa lai pẹ yi lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o fi oogun apẹfọn ti wọn n pe ni ọtapiapia sinu ounjẹ iya-baba to bii lọmọ, lati pa a arugbo naa danu.
Adugbo kan ti wọn n pe ni Granville to wa lagboole Abonnema, ipinlẹ Rivers niṣẹlẹ naa ti waye nigba ti wọn sọ pe iya arugbo ti oju n dun naa ran ọmọdebinrin lounjẹ, nigba to si maa gbe ounjẹ wa fun mama yi, o ti fi oogun apẹfọn naa sinu ẹ.
Oorun ti wọn sọ pe mama naa gbọ lo mu ko gbajare pe kawọn araadugbo gba oun lọwọ ọmọ-ọmọ oun to fẹẹ gba ẹmi oun lojiji.
Adura ti wọn lawọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa n gba ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ka bimọ to maa pa wa danu.
No comments:
Post a Comment