Ẹ WAA GBỌ NNKAN TI ỌGA BELOO ATI MADAMU ṢAJẸ SỌ NIPA IKU DAGUNRO, ATI AṢIRI IKU TO PA A - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 13, 2019

Ẹ WAA GBỌ NNKAN TI ỌGA BELOO ATI MADAMU ṢAJẸ SỌ NIPA IKU DAGUNRO, ATI AṢIRI IKU TO PA A

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Fasasi Ọlabankẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Dagunro. 
Bo tilẹ jẹ kii tun un ṣe iroyin tuntun mọ pe ilu mọn ọn ka agba oṣere tiata nni, Oloogbe Ọlabankẹwin Fasasi ti jade laye laarọ onii, Tọside tii ṣe ọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, ṣugbọn sibẹ, bi ala lo ṣi n ri loju ọpọ awọn oṣere tiata, paapaa awọn ifẹ lati maa wo o sinima agbelewo.

Ni nnkan bi aago marun kọja iṣeju diẹ laarọ onii, la gbọ pe ọkunrin naa dagbere faye patapata latari aisan ọlọdun pipẹ kan ti wọn lo ti n ba a finra, eyi ti wọn loo pada ran an lọ sọrun aremabọ.

Dagunro tọjọ ori ẹ ti le laadọrin ọdun diẹ la gbọ pe ọdun 1967 lo bẹrẹ iṣẹ tiata nigba to ṣi wa nileewe alakọọbẹrẹ, to si ti gbe akaikatan fiimu agbelewo jade, yatọ sawọn fiimu to ti kopa nibẹ.

Lara awọn to gba ara Oloogbe Dagunro jade ni: Murphy Afọlabi, Muyideen Ọladapọ (Lala), Lukmọn Raji, Kamilu Kọmpo, Ademọla Tijani atawọn min in, to fi mọ ọmọ ẹ, Jamiu Ọlabankẹwin.

Iluu Ekoo la gbọ pe ọkunrin naa dakẹ si, iyẹn nile ẹ, latari aisan kan ti wọn sọ pe ọpọlọpọ owo ni wọn ti naa lee lori, ko too kuro nidi iṣẹ tiata lọdun bii mẹta sẹyin.

Agbara oṣere nni, Alaaji Adebayọ Salami tọpọ awọn to n wo sinima daadaa mọ si Ọga Bello lo ti sọ iku Dagunro dun oun de gongo, nitori pe ko sẹni to mọ aṣa a gbe larugẹ bii Dagunro nitori pe pupọ awọn fiimu ẹ lo jẹ pe nipa iṣẹṣe ni, ati pe ogbontarigi to mọ nipa gbigbe iṣẹmbaye Yoruba larugẹ ni.

Ọga Bello tẹsiwaju pe Dagunro jẹ oninu ire, to si ko awọn eeyan mọra, ẹni ti kii fi igba kan bo ekeji ninu fawọn to ba sunmọn ọn, ati pe aṣaaju ni nidi iṣẹ tiata, nitori pe iwa itẹriba ẹ fawọn to ba nidi iṣẹ naa, paapaa oun (Ọga Bello), tawọn ko si le gbagbe ẹ titi aye.


Nigba toun naa n sọrọ, agba oṣerebinrin nni, Alaaja Fausat Balogun tawọn eeyan tun n pe ni Madamu Ṣajẹ, jẹ ko di mimọ pe eeyan to to ṣee gbe ara le ni Oloogbe Dagunro jẹ nigba to wa laye nitori pe ko ni i purọ fun un yin, bẹẹ ni ko nii jẹri eke tabi ṣe abosi.

Madamu Ṣajẹ tẹsiwaju pe ọpọ awọn eeyan lo ti dide lati ara oloogbe naa, paapaa nidi iṣẹ tiata ti wọn si ti di gbajumọ, ti wọn n ṣe daadaa, ko da tawọn ko si le gbagbe awọn ipa to ti ko.
  
Diẹ lara awọn sinima ti Oloogbe Dagunro ṣe ko too jade laye ni: Ija Abija; Dagunro; Jagunmolu; Ibinu Ọmọ Ẹlẹyẹ, Abẹni Agbọn, Kakaki 'leku, Ikilọ Agba ati Inu bibi.

Ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ onii la gbọ pe wọn yoo sinku ọkunrin naa nilẹ rẹ to wa ni Oṣogbo, tawọn oṣere tiata kaakiri si ti tẹkọ leti lọ sibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI