Lọjọ Tọside to kọja yi lọwọ awọn ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu, iyẹn EFCC tun tẹ awọn ọdọmọkunrin mejidinlogun ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara, Yahoo-Yahoo lọ.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Parliamentary Extension, Akai Efa niluu Calabar, ipinlẹ Cross River laṣiri wọn ti tu, lẹyin tawọn kan ti wọn lolobo pe ayekaye lawọn eeyan naa n jẹ kaakiri adugbo, ti wọn ko si fawọn araalu lọkanbalẹ.
Endurance Ahunwan, ọmọdun mejidinlọgbọn (28); Nohuwan Frank, ọmọdun mẹrindinlọgbọn (26); Dominic Chidiebere, ọmọdun mejidinlọgbọn (28); Idehe
Efosa, ọmọdun mẹtadinlogun (17); Patrick Edos, ọmọdun mẹtadinlọgbọn (27); Samuel Ukiwe, ọmọdun mọkanlelogun (21) ati Michael Edward, ọmọdun marundinlọgbọn (25).
Awọn yooku ni Destiny Efe, ọmọdun mẹtadinlọgbọn (17); Hope Yusuf, ọmọdun mọkandinlogun (19); Harrison Esi, ọmọdun mẹtadinlogun (17) ati Igbinigun Osamudia toun jẹ ọmọdun mẹtadinlogun
(17).
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni: ẹrọ kọmputa alagbeeka mẹwaa (10 laptops); ẹrọ ti wọn fi n wọ ayelujara (internet modems) mẹjọ; oriṣiriṣi foonu alagbara mẹkanla, atawọn nnkan ti wọn fi n lu jibiti.
Yatọ sawọn tọwọ tẹ yii, wọn tun ko awọn min in ni nnkan bii aago marun un aarọ ọjọ Fraide ijẹta nibi ti wọn n gbe lopopona
Ihejirika Close, Becky, Karu, nipinlẹ Nasarawa.
Awọn naa ni: Peter Olu Tsetimi,
Ogunbiyi Adekunle A, Emuze Omosigho Emmanuel, Isaac Daro Obozokhai, Samuel Nana-Kofi
Eruese, Edward Yusuf ati Peace Manayin toun jẹ obinrin.
No comments:
Post a Comment