Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti fi ọrọ ikilọ ranṣẹ si ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Saheed Akanbi Arowolo, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Arẹmọ pe oun ko fẹẹ ri mọ lagbegbe toun ba wa, nitori pe gbogbo araalu ti kẹhin sii.
Ohun ta a gbọ ni pe latari awọn aṣemaṣe kan ti wọn ni Ọgbẹni Arẹmọ yi hu, lo mu ki gbogbo awọn ara agbegbe Itele to wa niluu Ọta, iyẹn ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta kẹhin si ọkunrin naa gẹgẹ bi olori wọn.
Onii lawọn agbaagba atawọn oloye lagbegbe naa ko ara wọn lọ silẹ Oloye Ọbasanjọ lati lọọ foju awọn adari tuntun han fun un, pe awọn ko ni nnkankan ṣe pẹlu awọn adari tawọn ni tẹlẹ mọ, ko si ma ṣe maa ri wọn gẹgẹ bi aṣiwaju agbegbe naa mọ.
Alaaji Bamiṣẹbi Taofeek Adeyẹmi ati
Alaaji Kazeem Ajiboye tawọn eeyan tun n pe ni Oluọmọ lawọn adari tuntun naa ti wọn lọọ fi han Aarẹ tẹlẹri naa, lẹyin ti wọn ti fi iwe tiluu atawọn aṣoju agbegbe Iga meje bu ọwọ luu naa han Ẹbọra Owu lọjọ Tọside ana.
O wa a gba wọn lamọnran pe ki wọn kun fun ọpọlọpọ ikiyesara nipa awọn adari tuntunt ti wọn ṣẹṣẹ yan naa, ki wọn ma ba a tun bọ sọwọ awọn ti wọn ti foju wọn gbolẹ bii tawọn ti ṣaaju.
Awọn ta a gbọ pe wọn bu ọwọ luu awọn adari tuntun naa ni: Ọmọba Amosu, Sansaliu Bamiṣẹbi, Alaaji Taofeek Bamiṣẹbi, Alaaji Kazeem
Ajiboye, Nureni Lubatu, Arabinrin Wusamọt Akinṣile, Arabinrin Isimọt Ọṣhọ, Arabinrin Ajimọh Ọlaikan.
Awọn min in ni: Naoh Bamiṣẹbi, Babatunde
Akinṣile Ọduntan, Lukman Dada, Balogun Saheed Ọduntan, Balogun Jẹlili Ọduntan, Balogun Ọlatunji Ọduntan, Mọnsuru Obi
Ajiboye, Ṣarafa Ogunlẹyẹ Ajiboye, Oloye Ajani Bamiṣẹbi, Samson Ọṣhọ, Saudatu
Bamiṣẹbi ati Abdullai Lukmọn.
Awọn yooku ni: Wasiu Ajiboye, Gafar Ọduntan, Bello
Yussuf, Sule Salami, Saheed Bamiṣẹbi Musibau Bamiṣẹbi, Tawak Bamiṣẹbi ati
Kamilu Bamiṣẹbi.
No comments:
Post a Comment