Ẹ PADE ỌNỌREBU TO GBE APOTI FUN ỌDUN MẸRINDINLOGUN KO TOO WỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 8, 2019

Ẹ PADE ỌNỌREBU TO GBE APOTI FUN ỌDUN MẸRINDINLOGUN KO TOO WỌLE

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Loootọ ni wọn maa n sọ pe ẹyin oni suuru ni Ọlọrun wa, ati pe ẹni to ba duro ti Oluwa, kii j'ogun ofo, bakan naa ni wọn lawọn kan tun ma n jẹ ko di mimọ pe pe apẹ ko too jẹun kan ko ni i jẹ ibajẹ.

Wọnyi gan an lọrọ to lọ nibamu pẹlu itan igbesi aye ọkan lara awọn ọnọrebu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọyọ, Ọnọrebu Akeem Ọlalẹyẹ Ọbadara.

Ọdun 1999 ni Ọnọrebu Akeem Ọbadara kọkọ gbe apoti ibo lati ṣoju awọn ara agbegbe Ibadan North West nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.

Ọnọrebu Ọbadara padanu ipo naa sọwọ alatako ẹ nigba naa, bẹẹ lo gbe apoti lọdun 2003, 2007, 2011, 2015 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ti ko wọle, ṣugbọn to pada tun gbe apoti yi ninu idibo ọdun 2019, tawọn araalu si sọ pe asiko naa ti to fun un lati ṣoju wọn.

A ti ẹ gbọ pe oriṣiriṣi ẹgbẹ oṣelu ni wọn ti parọwa si gbajumọ oloṣelu yi pe ko wa a adarapọ mọ wọn, ṣugbọn to fariga pe oun ko le dalẹ ẹgbẹ oṣelu PDP toun ti bẹrẹ oṣelu.

Ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ pẹlu Ọnọrebu Ọbadara n bọ laipẹ, ẹ ku oju lọna.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI