A fi kawọn to n wa iṣẹ ijọba,
paapaa awọn to ti kẹkọọ gboye nipinlẹ Ogun lọ maa gbaradi bayii, nitori pe
ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe eto igbanisiṣẹ yoo bẹrẹ laipẹ, ati pe ko din lẹgbẹrun
mẹwaa oṣiṣẹ tawọn fẹẹ gba.
Eyi to n jẹ idunnu awọn araalu
ninu gbogbo ẹ ni bijọba tun ṣe sọ pe kii ṣe pe awọn akẹkọọ gboye nikan loun fẹẹ gba, bi ko ṣe pe gbogbo
awọn to ba ni akikanju, yala, wọn ka iwe, tabi wọn ko gba ile ẹkọ kọja rara,
ṣugbọn ti wọn mọ ọwọ yipada lawọn fẹẹ gba siṣẹ.
Akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni
Kunle Ṣomọrin lo gbe ọrọ naa sita lẹyin ipade ti Gomina Dapọ Abiọdun ṣe pẹlu
awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC niluu Abẹokuta, nibi to ti mẹnuba ọrọ naa.
No comments:
Post a Comment