Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe
Mọshood Kaṣhimawo Ọlawale Abiọla, ẹni tawọn eeyan nigbagbọ pe oun lo jawe
olubori ninu idibo Aarẹ tọdun 1993, Arabinrin Ọmọlọla Abiola-Ẹdẹwọr ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu bo ṣe bu ọla, iyi ati
ẹyẹ fun baba ẹ lẹyin ọdun mọkanlelogun to ti jade laye.
Bẹ o ba gbagbe, oriṣiriṣi ipa
ni Aarẹ Buhari ko lati jẹ ki iranti Oloogbe MKO Abiọla wa niranti awọn ọmọ
Naijiria kaakiri agbaye, to si tun sọ ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdọọdun di ayajọ eto
oṣelu awaarawa, atawọn min in bẹẹ.
Arabinrin Abiọla-Ẹdẹwọr tun wa
a rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria jakejado pe ki wọn ba oun gbe osuba nla fun
Aarẹ Buhari, nitori pe titi lai niranti ẹ yoo fi wa ninu iran Abiọla atawọn ọmọ
Naijiria.
Ninu atẹjade to pe ni ti
obinrin naa gbe sita lọjọ Fraide ana, eyi to pe ni “JUNE 12 – President Muhammadu Buhari rekindles
Nigeria’s Hope” lo ti jẹ ko di mimọ pe pẹlu
awọn nnkan Aarẹ Buhari ṣe, o ti mu ki oku ọrun ti idibo ti wọn fagile naa lọọ
sinmi ayeraye.
No comments:
Post a Comment