Ọrọ naa kii ṣoju lasan lohun ti ọpọ awọn to gbọ siṣẹlẹ kayeefi n sọ nigba ti wọn gbọ pe ọkan lara awọn ọlọpaa ti wọn le danu lẹnu iṣẹ ynbọn pa iya-iyawo to fẹẹ fẹ loṣu kejila ọdun to kọja.
Ohun ta a gbọ ni pe lọdun to kọja ni Christian pẹlu iyawo afẹsọna ẹ, Blessing mu ọjọ igbeyawo, ti wọn si lawọn mọlẹbi awọn mejeeji ti fọwọ sii, ṣugbọn ti wọn sọ pe iya Blessing, Arabinrin Veronica Obiejieogo ko fọwọ si fifẹ wọn.
Wọn ni gbogbo igbesẹ ni Christian ti gbe lati jẹ ki iya Blessing gba koun fẹ ọmọ ẹ, ṣugbọn ti kii fẹ ẹ rii soju.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun to kọja la gbọ pe wọn fi ọjọ igbeyawo naa si, ti wọn si ni Christian ti na ọpọlọpọ owo, ko da ti wọn loo tun fun Blessing lowo awọn nnkan ti wọn maa nilo lọjọ naa.
Nigba tọrọ maa yiwọ, wọn ni Blessing ko de ile Christian mọ, ti ko si tun gbe foonu lati ba Christian sọrọ titi tọjọ igbeyawo naa fi wọle, to si kọja. Nigba to si rii pe oun ko gburo iyawo toun fẹẹ fẹ, lo ba gba ile iya Blessing lọ.
Wọn ni pẹluu ibinu lo fi lọ lọjọ naa pẹluu ibọn ilewọ, gbogbo bi wọn ṣe sọ pe Christian n sọrọ ni wọn iya Blessing ko da a lohun, to mu ko yinbọn fun un nikun.
Latigba naa ni wọn sọ pe Christian ti na papa bora, tawọn yẹn si ti gba teṣan ọlọpaa lọ lati lọọ fẹjọ sun, ṣugbọn ti wọn ko rii di ọsẹ to kọja yi. Iluu Por Harcourt la gbọ pe wọn ti kofiri ọmọdun mọkandinlogoji naa.
Ohun ta a gbọ ni pe ọdun 2005 ni wọn ti le Christian kuro nidi iṣẹ ọlọpaa, to si ti lu awọn eeyan ni jibiti loriṣiriṣi kọwọ too tẹ ẹ.
No comments:
Post a Comment