EYI LAṢIRI IKU TO PA BABA ALAKOSO ṢỌỌṢI KERUBU ATI SERAFU LAGBAYE, ỌRỌ TI WỌN LOO ṢO KẸHIN RE E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 9, 2019

EYI LAṢIRI IKU TO PA BABA ALAKOSO ṢỌỌṢI KERUBU ATI SERAFU LAGBAYE, ỌRỌ TI WỌN LOO ṢO KẸHIN RE E

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu ibanujẹ ọkan ni gbogbo ọmọ ijọ Kerubu ati Serafu kaakiri agbaye wa bayii, latari bi olori wọn patapata lagbaye, Alagba Joseph Oluṣẹgun Ṣonde ṣe fi aye silẹ lojiji.

Ni nnkan bi aago mẹrin idaji onii Sande la gbọ pe baba naa fi aye silẹ lẹyin aisan ranpẹ ti wọn loo da a dubulẹ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun (87) ni Baba naa ko too ku, ta a si gbọ pe aisan ọjọ ogbo lo ṣe e, ti kii si i ṣe pe boya wọn n gbe kaakiri lati na owo lee lori fi tọju ẹ, tabi pe wọn bẹbẹ owo fun un.

AWIKONKO gbọ pe Oloogbe naa ni oludasilẹ ṣọọṣi Kerubu ati Serafu, ẹka ti Ẹbenezar Communion to wa ladugbo Oke-Ibukun, Aṣero niluu Abẹokuta, to si gbajumọ daadaa.

Nnkan ti wọn lo n ṣe awọn to wa lẹgbẹ baba naa ni kayeefi kẹlẹmi in too gba ni ọrọ ti wọn loo sọ kẹhin pe "Mo dupẹ lọwọ ẹ, Ọlọrun", eyi gan ani lo jẹ ki wọn mọ pe aya Olugbala ni baba naa ti lọọ sinmi in ayeraye.

Gbogbo bi eto isinku Alagba Ṣonde yoo ba ṣe lọ sii lao maa mu wa fun un yin lakọtun. Ẹ ku oju lọna.

AWIKONKO n fi asiko yi ki gbogbo ọmọ ijọ Kerubu ati Serafu kaakiri agbaye pe wọn ku ara-fẹ-ra-ku o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI