AYẸYẸ ỌDUN EGUNGUN N'IBADAN: EMI KO LE LỌ SI TẸṢAN ỌLỌPAA LỌỌ DỌBALẸ O - OLUBADAN PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 10, 2019

AYẸYẸ ỌDUN EGUNGUN N'IBADAN: EMI KO LE LỌ SI TẸṢAN ỌLỌPAA LỌỌ DỌBALẸ O - OLUBADAN PARIWO SITA

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Ọba Saliu Adetunji ti pariwo fawọn araalu, paapaa awọn ọdọ kaakiri pe ki wọn ma ṣe lo anfaani ayẹyẹ ọdun Egungun to bẹrẹ lati fi huwa jagidijagan, nitori pe akoba nla lo maa n jẹ fun ilu ati orilẹ-ede ẹni.

Ọjọ Sande ana, ni Kabiyesi Olubadan tiluu Ibadan sọrọ yi jade ninu Aafin ẹ to wa ni Popoyemọja pe asiko lati tun ranti ọkan lara awọn aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba lo de, tawọn si gbọdọ fi iwa ọmọluabi ṣe e.

Nilẹ Yoruba patapata, ko fẹẹ le si iluu kan ti wọn kii ti i ṣe ọdun Egungun, to si jẹ ọkan pataki lara awọn aṣa ilẹ Yoruba tawọn eeyan nṣe ju.

Bẹ o ba gbagbe, lọdun to kọja ti wọn ṣayẹyẹ ọdun Egungun yi, ọpọlọpọ wahala ni wọn fi ayẹyẹ naa da silẹ, ti wọn si dukia ti ko din ni miliọnu naira jẹ.

Eyi gan an lomu ki Ọba Salisu Adetunji tii ṣe Olubadan tiluu Ibadan tete ke gbajare sita lati rawọ ẹbẹ sawọn eeyan pe ki wọn jẹ ẹburẹ, ki wọn si lo anfaani naa la ti fi gbe aṣa Yoruba larugẹ, dipo ki wọn fi da wahala silẹ laarin ilu.

Siwaju siii ni Kabiyesi Olubadan tun rawọ ẹbẹ sawọn eeyan pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹluu awọn eleto aabo ti wọn ti mura silẹ lati jẹ ki ayẹyẹ naa lọ nirọwọ-irọsẹ.
  
Bẹẹ lo sọ pe lilo awọn nnkan ija oloro bi ibọn, aake, igo, ada alaamu, ida, ọbẹ atawọn min in ni ko ba ofin aṣa ilẹ Yoruba, paapaa ofin orilẹ-ede Naijiria, to si loun ko ṣetan lati lọọ kawọn pọyin dọbalẹ lagọ ọlọpaa lati gba eeyan tọwọ ba tẹ silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI