Kani baale ile kan to n fiṣẹ agbẹjọro lu awọn araalu ni jibiti ni, boya ki ba ti tete jawọ ninu iwa ibajẹ naa ko too di pe akara rẹ yoo tu sepo, ati pe awọn kan ni wọn maa da aṣa pe 'ori to ba maa jẹ ikoo, bi iru ori bẹẹ ba we igba lawaani, yoo ṣi'.
Wọn yi lọrọ to lọ nibamu pẹlu bọwọ ṣe tẹ ayederu agbẹjọro kan ta a ko tii mọ orukọ ẹ di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan, to si mu kawọn eeyan maa fi epe nla-nla ranṣẹ sii pe ko nii bọ ninu wahala naa.
Ohun ta a gbọ ni pe lọjọ Fraide ijẹta yi laṣiri ayederu agbẹjọro naa tu ni kọọtu Majisireeti to wa ni Ifọ lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ.
AWIKONKO gbọ pe ṣe lọkunrin naa lọọ gbe lẹyin awọn kan ti wọn gbe ẹjọ lọ si kọọtu, asiko to n sọrọ lọwọ ni wọn sọ pe ọrọ to n sọ ko tọ si agbẹjọro gidi lẹnu, to si mu ki adajọ ile ẹjọ naa bẹrẹ sii beere oriṣiriṣi ibeere lọwọ ẹ, ti wọn si ni ko le dahun.
Oriṣiriṣi irọ ni wọn sọ pe ọkunrin naa n pa ni kọọtu, to si mu ki adajọ fibinu ranṣẹ sawọn ọlọpaa to wa lọgba kọọtu naa, loju ẹsẹ ni wọn ti ko ṣẹkẹṣẹkẹ sii lọwọ, ti wọn si ni ki wọn loo ju satimọle.
No comments:
Post a Comment