Ṣe lawọn eeyan kawọ mọri nile ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Ilọrin lọjọ laarọ onii Tuside, nigba ti Onidajọ Mahmud Abdulgafar sọ pe oun ko ni faaye silẹ fun ọdọmọkunrin kan, Temitọpẹ Charles ti wọn fẹsun gbajuẹ ori ayelujara kan pe ki wọn gba beeli ẹ, dipo bẹẹ ko lọọ fi ẹwọn ọdun marundinlogoji (35) gbara.
Ohun ta a gbọ ni pe ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun yi ni ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo kumọ-kumọ, iyẹn EFCC tẹ Temitọpẹ, ọmọdun mejilelogun ti wọn ni orukọ kan ti wọn pe ni Teresa Simon lo fi n lu jibiti lori ayelujara.
Bẹẹ ni wọn tun ka oriṣiriṣi awọn ayederu iwe to ti fi lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara naa, eyi ti wọn loo tako ofin lilu jibiti, to si mu ki wọn fẹsun marun un ọtọọtọ to nii ṣe pẹluu jibiti kan an.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Mahmud Abdulgafar sọ pe ọdun meje-meje pere ni ki Temitọpẹ fi lọọ gbara lori awọn ẹsun marun un ọtọọtọ naa, eyi ti gbogbo ọdun naa jẹ ọdun marundinlogoji.
Onidajọ naa sọ pe awọn ẹri ti ajọ naa fi tako ọdaran naa lo jẹ eyi to peregede, ti ko si ni ayidayida ninu, ati pe ọdaran funra ti sọ pe oun jẹbi awọn ẹsun naa, nitori naa, ko lọọ kẹkọọ siwaju sii lẹwọn.
No comments:
Post a Comment