AYE MA NIKA O, AṢIRI OLUKỌ-AGBA FASITI TO FẸẸ FIPA BA AKẸKỌỌ SUN TU NIHOHO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 15, 2019

AYE MA NIKA O, AṢIRI OLUKỌ-AGBA FASITI TO FẸẸ FIPA BA AKẸKỌỌ SUN TU NIHOHO

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Ihoho ọmọluabi bayii ni wọn ka olukọ-agba kan nile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ Ekiti (Ekiti State University), Dọkitọ O. O. Aduwo ti ẹka ikẹkọọ oluṣiro-owo (Accounting Department).

A gbọ pe o ti pẹ ti Dọkitọ Aduwo ti wa lẹnu iwa ibajẹ naa, ẹni ti wọn loo kundun lati maa bawọn akẹkọọ-binrin sun, ko le fun wọn ni maaki, ṣugbọn eyi to ṣe gbẹyin yi lo buu lọwọ, nigba t a agbọ pe ṣe ni wọn dọdẹ ẹ lati muu, ki wọn si foju ẹ han sita.

Ekiti State University Lecturer caught 
Akẹkọọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Nikẹ ni wọn sọ pe Dọkitọ naa fọngbọn tan lọ silẹ ẹ lana tii ṣe Fraide, lati ba a laṣepọ, ṣugbọn ti wọn loun naa ti fi to awọn ọrẹ rẹ lọkunrin ati lobinrin leti.

AWIKONKO gbọ pe Nikẹ ko kọkọ gba lati lọ sile Dọkitọ Aduwo yi, ṣugbọn ti wọn ni ọrẹ-kunrin ẹ, atawọn ọrẹ rẹ sọ fun un ko lọ, ati pe awọn yoo tẹlẹ e lọ lati lọọ yẹyẹ ẹ. Idi ni yii ti wọn loo fi gba lati lọ.
Nigba ti wọn debẹ la gbọ pe Nikẹ wọle, tawọn ọrẹ rẹ si duro sita, bo ṣe to asiko diẹ la gbọ pe wọn sare wọle nigba ti wọn n gbọ ohun pe Dọkitọ Aduwo ti fẹ maa ko ibasun fun Nikẹ, ti wọn si bẹrẹ sii fi foonu wọn ya fidio iṣẹlẹ naa silẹ.

Bo ṣe rii pe aṣiri oun ti tu, lo ba bẹrẹ sii dọbalẹ bẹbẹ pe ki wọn pa oun sile, ki wọn ma pa oun sita, ati pe oun yoo fun wọn ni nnkan ti wọn ba n fẹẹ.

 
Nigba taṣiri maa luu sita, Nikẹ ni wọn loo gbe fidio naa sori ayelujara abanisọrọ, iyẹn Whatsapp lati jẹ kawọn eeyan mọ pe aṣiri Dọkitọ Aduwo ti tu sita.

Ohun ta a gbọ bayii ni pe ọkunrin naa ti na papa bora, ati pe awọn alaṣẹ Fasiti naa yoo gbe igbimọ iwadii dide lọjọ Mọnde to n bọ yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI