Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ko nii laju silẹ lati jẹ iwa ọdaran maa da alaafia ipinlẹ naa ru, fun idi eyi, wọn rawọ ẹbẹ si Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ naa, Bashir Makama pe ko sun ṣokoto ẹ daadaa lati wọya ija pẹlu awọn to ba fẹ maa da alaafia ilu laamu.
Nibi ijokoo tile igbimọ aṣofin naa jokoo gbẹyin yi ni wọn ti fẹnu ko pe ki wọn dide oogun sawọn to n huwa ọdaran bii ajagungbalẹ, ẹlẹgbẹ okunkun, paapaa awọn ẹgbẹ onimọto nipinlẹ naa ti wọn ba fẹẹ de wahala silẹ.
Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, Ọnọrebu kan to n ṣoju ẹkun Ọbafẹmi Owode, iyẹn Ọnọrebu Ṣonẹyẹ
Kayọde lo daba naa, ti Ọnọrebu Sọlomọn Ọṣhọ toun n ṣoju ẹkun Rẹmọ North lo keji aba ẹ, ko too di pe gbogbo ile fọwọ sii pe awọn iwa naa ti n kọja oju tawọn fi n wo o.
Loju ẹsẹ ni abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa, Ọnọrebu Ọlakunle Oluọmọ fi aṣẹ sii pe ki igbesẹ naa bẹrẹ, ti wọn si tun rawọ ẹbẹ sii gomina ipinlẹ naa, Ọmọba Dapọ Abiọdun pe ko tete fọwọ sii ni waranṣeṣa.
No comments:
Post a Comment