O TAN O: AARẸ BUHARI TU AṢIRI AWỌN TO N DA NAIJIRIA RU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 13, 2019

O TAN O: AARẸ BUHARI TU AṢIRI AWỌN TO N DA NAIJIRIA RU

Buhari on Democracy Day 
Ana tii ṣe ayajọ ọjọ etoo oṣelu awaarawa ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Ọgagun Muhamadu Buhari ti tu pẹrẹpẹẹrẹ lori awọn to wa nidi bi wọn ṣe n ba eto aabo orilẹ-ede yi jẹ, to si lawọn alagbara nla ni wọn wa nidi ipaniyan, ijinigbe ati iwa buruku oriṣiriṣi.

Buhari jẹ ko ye ọpọ awọn to n gbọ ọ lasiko to n sọrọ naa pe ibi tawọn to wa nidi madaru yi ti n jẹun niyẹn, ti wọn si n fa ọwọ aago ilọsiwaju wa sẹyin.

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe pẹlu bawọn alagbara naa ṣe n yọwọ-kọwọ, iyẹn ko di igbesẹ lati mu awọn ileri toun ṣe lasiko ipolongo ibo saa ẹlẹẹkeji ṣẹ nipa eto aabo to peye, eto ọrọ aje to ye kooro ati gbigbogun ti iwa ajẹbanu.

Ninu ọrọ Aarẹ Buhari, o sọ pe "Nigba ti mo n bura niwaju gbogbo ọmọ Naijiria lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2015, aisi eto aabo lo n jọba. Yatọ si pe wọn ti gba ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa ni Northeast, Awọn Boko Haram lanfaani lati kọlu ilu kiluu to fi mọ oluu-ilu wa l'Abuja.

"Bi wọn ṣe n dunkooko mọ wa, naa ni wọn tun n ju bọmbu lati dana sun dukia atawọn eeyan, to fi mọ olu-ileeṣẹ ọlọpaa Abuja.

"Mo gba pe awọn ipenija ati ibi ti eto aabo ku si ni ti bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe lawọn agbegbe kan lorilẹ-ede yi, ti wọn si tun n pawọn eeyan nipakupa. Iyatọ nla to wa laarin ọdun 2015 si onii ni pe a n ri anfaani ifọwọsowọpọ nla lawọn ẹka eleto aabo nipa ti ọrọ owo, irinṣẹ ati idagbasoke nipa iriri iṣẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI