AṢIRI KAREEM, OGBOLOGBO ADIGUNJALE TU SỌWỌ SO SAFE NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 16, 2019

AṢIRI KAREEM, OGBOLOGBO ADIGUNJALE TU SỌWỌ SO SAFE NIPINLẸ OGUN

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

"Ẹ ṣaanu mi, ẹ foju aanu wo mi, mo ti yi pada" lọrọẹbẹ ti wọn lo n tẹnu ọdọmọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Abimbọla Kareem jade nigba tọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo SO SAFE tẹ ẹ lọjọ Satide ana an.

Ni nnkan bi aago kan oru la gbọ pe ọwọ tẹ Kareem ti wọn lo n gbe ladugbo Igboku Adebayọ to wa nijọba ibilẹ Ipokia, Idiroko lasiko to n bọ lati ibi to ti lọọ jale nile mẹta ọtọọtọ.


Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ẹgbẹ SO SAFE, Ọgbẹni Mọruf Yusuf ṣe fi to wa leti, o ni ogbologbo ọdaran paraku ni Kareem, to si ti wa lẹnu iṣẹ naa ti pẹ, ṣugbọn ti omi pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ ẹ nigba tọwọ tẹ ẹ.

O lawọn nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ ni Ẹgbẹrun marun aabọ (5,450) naira, Kọmputa alagbeeka kan, Foonu Techno kan, Bata oriṣi meji ati ṣokoto oriṣi mẹta min lasiko tọwọ tẹ.

Ọgbẹni Mọruf tun fidi ẹ lelẹ pe lẹyin iwadii awọn lawọn ṣẹṣẹ fa a le awọn ọlọpaa ẹkun Idiroko lọwọ lati ṣiṣẹ ti wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI