Gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Ọgbẹni Fasasi Ọlabankẹ tọpọ awọn eeyan mọ si Dagunro ti jade laye, to si ti ko ọpọ awọn oṣere ẹgbẹ ẹ sinu ironu titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii gbọ kulẹkulẹ nipa iku Dagunro, ọmọ bibi ilu Oṣogbo naa, 'sugbọn ta a gbọ pe ana tii ṣe Wẹside ni ọkunrin naa ki aye pe o digboṣe.
Ọkan lara awọn oṣere tiata ẹgbẹ ẹ, to tun jẹ bi ọmọṣẹ fun un, Adekọla Tijani lo gbe iroyin naa sori ikanni ayelujara lati jẹ ko di mimọ fawọn eeyan pe ọkunrin naa ti ta teru nipa.
Sinima babalawo lọpọ awọn eeyan mọ ọkunrin naa mọ.
Ẹkunrẹrẹ iku to pa Dagunro n bọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment