Ọlaide Ọṣinuga, Ekoo
Baba agbalagba arugbo ẹni ọdun mejilelaadọrin kan, Jacob Ade Farinde ti wa lahamọ ọlọpaa bayii, to n fojoojumọ bẹbẹ fun oju aanu latari bo ṣe fun ọmọdebinrin kan ti wọn pe ni Bunmi loyun, to si tun paa danu toyun-toyun.
Jacob Farinmade ni oludasilẹ ṣọọṣi Celestial Church of Christ, Gospec Mission to wa lagbegbe Mosan,
Ipaja nipinlẹ Ekoo.
Ohun ta a gbọ ni pe latigba ti wọn ti le Bunmi danu nile ẹkọ fasiti Babcock lọdun 2014 ni baba ẹ ti sọ pe ko lọ maa gbe lọdọ iya ẹ, tori pe oun ko fẹẹ rii, paapaa bi wọn tun ṣe ni aisan kan wa lara ẹ.
Lẹyin naa la gbọ pe iya Bunmi, Arabinrin Derayọ Omiṣipi mu ọmọ rẹ gba ṣọọṣi lọ pe ki Wolii Farinmade ba oun gbadura fun un, ko si tun ṣiṣẹ iṣegun fun un pẹluu.
Ṣugbọn kaka ki Farinmade ti wọn loo ti ni iyawo mẹwaa sile ṣiṣẹ ti wọn gbe fun un, ṣe lo n fojoojumọ ba Bunmi laṣepọ, titi tiyẹn fi loyun mọ ọn lọwọ.
Wọn ni lọjọ ti Bunmi bẹrẹ sii rọbi, Farinmade ni wọn loo gba ẹbi fun un, tiyẹn si ku mọn ọn lọwọ. Ni kete to rii pe Bunmi ti dake, lo ti sare gbe e gba ẹyinkule ilẹ rẹ lọ, to si lọọ sin in loru ọganjọ lati ṣe ọrọ naa ni oku oru.
NIgba ti wọn ni iya Bunmi ko ri ọmọ ẹ, to si n fojoojumọ beere lọwọ pasitọ yi, lo ba jẹwọ fun un pe ọmọ naa ti ku toyun-toyun, ati pe ko jẹ kawọn ṣe ọrọ naa ni mẹnumọ.
Igbe ikunlẹ abiyamọ ni wọn sọ pe iya Bunmi ke lọ tẹṣan ọlọpaa, tawọn yẹn si lọọ gbe e nile ẹ to wa ninu ṣọọṣi nibẹ.
No comments:
Post a Comment