Aṣe tẹni to de laari, a ko mọ tẹni to n bọ. Ẹgbẹ
agbabọọlu Arsenal naa ti tẹle Manchester United lọ si idije Europa.
Arsenal naa ta ọmi ayo kọọkan pẹlu ikọ agbabọọlu
Brighton ni papa iṣere Emirates, eleyi to tumọ si pe wọn ko le de ipo kẹrin mọ
lori tabili idije Premier League fun saa yii.
Ẹlẹsẹ ayo Pierre-Emerick Aubameyang lo kọkọ gba
pẹnariti sawọn fun Arsenal lẹyin iṣẹju mẹsan an ti ere bọọlu naa bẹrẹ.
Ṣugbọn Glenn Murray dayo ọhun pada lẹyin to yẹ ile
Arsenal pẹlu pẹnariti ti wọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Brighton.
Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti dero Europa
League bayii lẹyin ti wọn ta ọmi alayo kọọkan pẹlu Huddersfield Town.
Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ti ṣakoba fun ikọ Man U lati kopa
ninu idije Champions League ni saa to n bọ.
Scott McTominay lo kọkọ gba goolu sawọn fun
Manchester United lẹyin iṣẹju mẹjọ ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ṣugbọn Isaac Mbenza dayo naa pada lẹyin iṣẹju
mẹẹdogun ti abala keji ere bọọlu ọhun bẹrẹ.
Ẹgbẹ agbabọọlu Man U kuna bayii lati yege fun idije
Champions League ni saa ere bọọlu to n bọ.
Chelsea ati Tottenham ti wẹ tan kan-in kan-in bayii
lati ṣoju ilẹ Gẹẹsi ninu idije Champions League ni saa to n bọ.
- BBC
No comments:
Post a Comment