Ṣọọṣi, Mọṣalaṣi, ile bọọlu, ile igbafẹ awtọn agbegbe to ba mọ pe oun ti le jale ni wọn loo fẹran lati maa lọ, to si maa da ṣiṣẹ ibi ẹ.
A gbọ pe o ti pẹ tawọn ọdọ ilu naa, atawọn ọlọpaa ti n ṣọ ogbologbo ọdaran naa.
Nigba ti ọwọ palaba ẹ maa segi, ọsan ana Fraide la gbọ pe 'One Man Squared' lọọ ra bẹntiroolu nile epo kan niluu Gboko naa, ibẹ lawọn ti wọn ti n ṣọ tipẹ ti kofiri ẹ, ko too ṣẹju pẹ, wọn bẹrẹ sii ju lokuta, titi to fi ku.
Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn pada wa a gbe oku ẹ lo si mọṣuari. Bẹẹ la tun gbọ pe oorun ayọ lawọn araalu naa sun mọju onii Satide nitori pe ohun ta a gbọ ni pe wọn kii sun wọra tẹlẹ.
No comments:
Post a Comment