Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yi,
afaimọ ki oogun abẹle min in ma tun pada bẹ silẹ lẹẹkeji lorileede Naijiria,
iyẹni bi ijọba Muhammadu Bauhari ko ba tete gbe igbesẹ lati kapa awọn Fulani ti
wọn fẹsun kan pe wọn ji awọn eeyan gbe kaakiri ilẹ Yoruba, ti wọn si n pa wọn
danu bi wọn ko ba tete ri owo gba lọwọ wọn.
Ẹgbẹ Igbimọ ọdọ Yoruba kaakiri
agbaye, iyẹn Yoruba Council of Youths Worldwide ṣe ti paṣẹ pe awọn ko fẹẹ ri
Fulani darandaran kankan to kere ju nilẹ wọn laarin ọjọ meje si asiko ta a wa
yi, bẹrẹ lati ana ti i ṣe ọjọ kẹtalelogun oṣu karun.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ
naa, Arẹmọ Oladọtun Hassan gbe jade sita,
eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti gbe eto kan kalẹ,
tawọn pe ni Eto F’ỌLUMỌ, iyẹn "Operation
Sweep Clean”, eyi to lawọn fẹẹ fi fọ ilẹ
Yoruba mọ kuro lọwọ awọn Fulani to n fojoojumọ da wọn laamu.
A gbọ pe ki i ṣe ẹgbẹ igbimọ
ọdọ ile Yoruba nikan ni wọn gbe eto yi kalẹ, wọn ni pẹlu ajọṣepọ awọn ọdọ
patapata nilẹ Yoruba, to fi mọ awọn akẹkọọ kaakiri orileede Naijiria ati
agbegbe ẹ lawọn panupọ, lati jẹ ki ofin orileede yi fẹsẹ mulẹ, lati daabo bo ẹmi
ati dukia awọn araalu.
Arẹmọ Oludọtun Hassan ninu
atẹjade naa fi ye wa pe lẹyin ipade tawọn ṣe lọjọ Tọside ana ni wọn ti bu ẹnu
atẹ lu awọn iwa buruku tawọn Fulani darandaran atawoọn Boko-Haraamu n hu, eyi
ti wọn ji awọn eeyan gbe bo sẹ wu wọn, ti wọn si ti fẹẹ gba ilẹ mọ wọn lọwọ.
O wa jẹ ko di mi mọ pe bawọn
ọdaran naa ko ba tete kuro lori ile wọn, iyẹn lawọn inu igbo ti wọn n sapamọ
sii ko too to ọgbọ ọjọ oṣu yi, iyẹn ọjọ Tuside to n bọ, gbogbo ẹ lawọn yoo tu,
tawọn yoo si doju ika kọ wọn gidigidi.
No comments:
Post a Comment