Ori lo kọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ kan ta a forukọ bo
laṣiri, eyi to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan laarọ oni, nitori pe asiko ti
wọn n gbaradi lati jade lọọ ṣere ni tirẹla oniyẹpẹ kan yawọ ọgba ile ẹkọ naa.
AWIKONKO gbọ pe ijanu tirẹla naa lo ja lojiji lori
ere ti wọn lo n ba bọ, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to wa leti. Opopona Ologunẹru lagbegbe
Ẹlẹyẹle niṣẹlẹ naa ti waye.
Wọn ni dẹrẹba tirela naa ma ba a kọlu awọn eeyan lo
mu ko yiwọ sẹgbẹ, to si lọọ kọlu fẹnsi ọgba ile ẹkọ naa.
Ohun tawọn eeyan n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ni pe ko ṣe
ẹnikẹni leṣe, depodepo pe eeyan yoo ku.
No comments:
Post a Comment