THERESA MAY, ADARÍ-BÌNRIN L'ÓRÍLẸ̀-ÈDÈ GẸ̀Ẹ́SÌ KỌ̀WÉ ÌFIPÒ-SÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OMIJÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 26, 2019

THERESA MAY, ADARÍ-BÌNRIN L'ÓRÍLẸ̀-ÈDÈ GẸ̀Ẹ́SÌ KỌ̀WÉ ÌFIPÒ-SÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OMIJÉ

Jọláadé Adélakùn, Ọ̀yọ́

Mínísítà Theresa sòrò ní 10 downing street, United Kingdom ojó etí tólo. Ó sowípé òhún ti sa gbogbo agbára tí ó wà níkápá òhún láti jékí áwon ará pálíáméntì fi enu won kò síbikan. Wón kùnà láti darí ará won kúrò nínú European Union tí àwon jé ikò brítéenì lará e. 

Mo tín gbìyànjú fún odidi odún méta séyìn. Sùgbón ní báyíi, n ó fipò sílè. Èyí yóo fàyègbà adarí míràn láti gorí àleifà. Máa sì máa sisé àrólé títítí á ò fi se ètò ìdìbò yan prime ministà tuntun. Ìfipò sílè mii yóò bèrè síi sisé láti ojó keeje, osù òkuukù, odún tí a wàa yíi.

Láti ìgbá tí mo ti dé ìjoba, mo tín tiraka kí United kingdom sisé, s'àafànní fún t'erú tomo, mùtú mùà láise fún áwon èeyàn kan à n yàa sótò.

Ní odún 2016, a fún àwon ará brítéenì láayè. L'ádúrú gbogbo ìkàsilè wa, wón dìbò láti fi European Union sílè.

Òdáa mi lójú lóni bíi tàtèyínwáa pé tí e bá fún àwon èeyàn láayè láti yàn, e ní láti f'ìdímúlè ohun tí won f'enukò sí.

Mo sì ti gbìyànjú láti se bee! 
Mo fikù lukùn kíkúròwaa nínu European Union tòhun-ti  ìbásepò waa pèlú àwon alábágbépò titun láti d'áabò bo isé, àjo àti ètò ìsó wa.

Moti gbìyànjú l'éemeta òtòotò láti jékí àwon pálíáméntì towó bo ìwé àdéhùn naa.

Momò pé ìfaradà dára kódà nígbà tí kòsí ònà àbájá kankan. Bayii ó ti wáa fojúhàn pé ohun tí yóo sisé fún ìlú nikí ó yan adarí tuntun.

Minista Theresa May tún se àfikún pé; Moti báa alagá egbé òsèlú mii f'enukò pé ètò ìdìbò yoo wáyé lósè tó n bò.

Moti sàlàyé fún Oloorì( Queen of England) gbogbo èróngba mii. Yóo maa dùmí loo títí lái pé n kò lé jísé Brexit.

Òdowó eni-léyìn-mi láti jékí gbogbo pálíáméntì f'enukò síbi ti yoo se ìlú loore. Ìfenukò lè wáyé tí apá kínní àti ìkejì bá fowó sowó pò, kí wón sì gbà fún ara won.

Èyí ni ìpè sí United Kingdom tí ó sisé fún gbogbo èeyàn. Mo ti ní àwon ìgbéga tí o wúni lórí láti odún méta séyìn.

A ti parí isé tí David Cameron àti George Osborne bèrè. Kùunà-kuuna waa tín parí lo. Gbèsè ìlú tín jáwá lè. Aadùn waa sì tín borí ìkorò.

Mo dálélórí ìpèsè isé gidi tín n lo déédé. Púpò èeyàn lóti rísé gbà tí o ti sowón di èeyàn pàtàkì lawujo.

Mo s'ètò ìkólé tí ó sìn tún ran àwon tí ó n sèsè kólé lówó. Ó n jé kí won o j'ànfànní tí àwon òbí won naa je.

A tún s'ètò àabò fún àyíká nípa dídíkùn ilè oníke, ìyípadè ojú òrun àti aféfé tín sara lóóre.

Èyí ni ohun tí ó ye ki ìjoba tí ó féràn ara ìlú àti ìdàgbàsókè orílé-èdè bójúto.

Mo nigbagbo pé egbé òsélú Conservative lè tún jísé Brexit, sin brítéenì pèlú ohun a yáayì (ètò àabò, ìtúsílè àti ànfànni). Àwon nnkan wònyí ni mo to ìpasè rè nínú iséjooba mi.

Máa fi isé yíi sílè níbáyì, ó tí jé ohun tí mo fi gbogbo ojó ayé mi pónlé. Èmí ni igbákejì prime ministà tí kòní jé enì keyìn.

Mo sèyí láisí èróngbà búburú bíkòse ìdúpé àti òríyìn láti lè l'anfanni a ti sin orílé èdè tí mo nife sí.

Omíje sì túnbo jadé lójú minista Theresa May  kí won tóo rìn kúrò lójú àgbáyé.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI