TAIWO MU ỌTI YO NI PATI ONI-PATI, NI ỌRẸ RẸ, ỌLỌHUNWA BA GUN-UN PA L'OGIJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 6, 2019

TAIWO MU ỌTI YO NI PATI ONI-PATI, NI ỌRẸ RẸ, ỌLỌHUNWA BA GUN-UN PA L'OGIJO

"Iṣẹ eṣu ni, mi o mọn ọn mọ, ẹ ma jẹ ki n ṣẹwọn lati kekere" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu ọdọmọkunrin kan tọjọ ori ẹ ko ju ọdun mejidinlọgbọn (28) lọ, Oni Ọlọhunwa nigba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, lẹyin to gun ọrẹ rẹ pa ni pati oni-pati.

Ọjọ Sande ana, ti i ṣe ọjọ karun un oṣu karun-un la gbọ pe Oni Ọlọhunwa ati ọrẹ rẹ, Baraka Taiwo jọ lọ si pati kan lagbegbe Ogijo. Ko pe ti wọn de pati naa la gbọ pe wọn ṣe faaji ara wọn daadaa, ti wọn si jẹun.

Nibi ti wọn ti n ṣe faaji yi lọwọ la gbọ pe Taiwo ti mu ọti yo bamu, to si n ṣe kati-kati, ko da a, ti wọn ni ṣe lo n da nnkan ru, tawọn eeyan to wa nibẹ si bẹrẹ si i fi ṣe yẹyẹ.

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ la gbọ pe Taiwo tun gbe ọti min in, to si fẹẹ ṣi, pẹlu ibinu ni wọn sọ pe Ọlọhunwa fi gba igo ọti naa lọwọ ẹ, pe ko tun gbọdọ mu ọti min in mọ, tori pe o ti yo kọja afẹnusọ, to ba si tun mu ọti min in, o le yiwọ mọ ọn lọwọ.

Ṣe la gbọ pe Taiwo koro oju pe ko jẹ koun mu ọti toun wa pati naa wa a mu gbadun, ati pe bi ko ba foun lọti naa mu, oun yoo la igo mọ ọn lori, gẹgẹ bi ọrọ ọlọti.

Eyi ni wọn sọ pe Ọlọhunwa gba sodi, to si fa ọbẹ yọ lapo, ko too di pe awọn mejeeji bẹrẹ si i fa ọrọ naa mọra wọn lọwọ. Ere lawọn eeyan kọkọ pe e, ayafi bi wọn ṣe sọ pe wọn gbọ ariwo 'oro o o o o'.

Kawọn eeyan to o ṣẹju pẹ, wọn ni Taiwo ti ṣubu lulẹ, bi wọn si ṣe maa gbe ẹ soke, ẹjẹ ti bo o, ki wọn to o ri i pe ṣe ni Ọlọhunwa fọbẹ gun un.

Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti gbe e digbadigba lati doola ẹmi ẹ, ṣugbọn ti ẹpa ko pada boro mọ, tọlọjọ si de si i. Bi Ọlọhunwa si ṣe ri i pe oun ti paayan, lo ba gbiyanju lati na papa bora, ko to o di pe wọn raa mu.

Ọkan lara awọn ti wọn jọ wa nibi iṣẹlẹ naa, Wasiu Raheem la gbọ pe o lewaju awọn ti wọn jọ ọ wa ni pati naa lọ teṣan ọlọpaa Ogijo, nibi ti wọn gbe Ọlọhunwa lọ, ta a si gbọ pe awọn ọlọpaa lo pada ni ki wọn gbe oku Taiwo lọ mọṣuari ọsibitu OSUTH lati ṣayẹwo ti wọn maa n ṣe lara oku.

Ni bayii, Kọmiṣana ọlọpaa, Bashir Makama ti paṣẹ pe ki wọn lọọ foju Ọlọhunwa bale ẹjọ fun idajọ ododo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI