Ninu isin ipade adura oloṣooṣu nni, iyẹn Agbara Gbọdọ Paarọ Ọwọ (Power Must Change Hands Programme) ni Dọkitọ Olukọya ti kede ọrọ naa fawọn ọmọ ijọ pe ki wọn lọ maa mura silẹ lati gbadura akanṣe, eyi ti yoo mu wọn bọ kuro ninu iṣoro oniruuru yoo wu ti wọn ba n koju.
Awọn adura oni 'S' meje naa lo pe ni:
i. SIN - Ẹṣẹ
ii. SETBACK - Ifasẹyin
iii. SHAME - Itiju
iv. SICKNESS - Aisan
v. STAGNANCY - Idaduro soju kan
vi. STOPERS - Awọn adaniduro
vii. SUFFER - Ipọnju
Dọkitọ Olukọya tẹsiwaju pe ipade adura toṣu kẹfa ni wọn yoo ti bẹrẹ sii gba awọn adura lori awọn nnkan wọnyii, to si lawọn ti ko ba ti n gbaawẹ ipade naa tẹlẹ ni ki wọn bẹrẹ sii gba a.
O jẹ ko di mimọ pe irugbin ko ni i jade lai gbaawẹ ati adura, nigba to n fi ẹsẹ bibeli (Matthew 17:21) ṣapẹẹrẹ fun wọn.
No comments:
Post a Comment