OWO TẸTẸ (BET9JA) RAN BAALE ILE LỌ SẸWỌN L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 11, 2019

OWO TẸTẸ (BET9JA) RAN BAALE ILE LỌ SẸWỌN L'ABẸOKUTA

Ana ti i ṣe Fraide ni ile ẹjọ Majisireeti to fikalẹ sagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta sọ pe ki baale ile ẹni ọgbọn ọdun kan, Taiwo Abiọdun lọọ gbatẹgun alaafia lẹwọn fun oṣu mẹta pere, latari owo tẹtẹ ti ko ri san.

Ọjọ karun oṣu yi, tii ṣe ọjọ Sande to kọja yi la gbọ pe Taiwo Abiọdun lọ si ṣọọbu Ọgbẹni Dare Kọmọlafẹ to wa ojule kẹta, adugbo Dele Afọlayan ni Ijeun Lukosi, to si ta tẹtẹ (Bet9ja), eyi ti wọn lowo ẹ jẹ ẹgbẹrun mẹtadinlogun (17,000) naira.

Wọn ni bi Taiwo ṣe ta tẹtẹ naa tan, to ku ko san owo, lo ba da ọrọ naa si agidi fun Dare, nigba to di pe iyẹn ko gba fun lati kuro nibẹ lai san owo, ni wọn ni Taiwo tun lo ọgbọn arekereke pe ki Dare tẹle oun lati wa lọọ gba owo iyawo oun nikorita adugbo naa.

AWIKONKO gbọ pe bi wọn ṣe debẹ ni Taiwo ti fẹẹ na papa bora, ṣugbọn ti wọn ni Dare dii mu pe ko ni i lọ, ayafi toun ba gba owo oun. Ko pẹ ni wọn sọ pe Taiwo bẹrẹ sii ko igbaju ati igbamu bo Dare, ko too di pe awọn araadugbo lọọ ba wọn.

Awọn eeyan yi ti wọn gbọ nnkan to ṣẹlẹ la gbọ pe wọn lọọ fa Taiwo le awọn ọlọpaa to wa nitosi lọwọ, ti wọn si jẹ ko ye wọn pe ṣe lo fi ọwọ ọla gba Dare loju.

Adajọ ile ẹjọ naa, Ọlanrewaju Ọnagoruwa ti wa a paṣẹ pe ki Taiwo lọọ jẹ igbadun oṣu mẹta pere lẹwọn, tabi ko san ẹgbẹrun mẹta owo faini, ko si tun san ẹgbẹrun mẹwaa naira fun Dare.

Agbẹjọro fawọn ọlọpaa, Boniface Agbọh ni ẹṣẹ meji ti wọn ka si Taiwo lẹsẹ tako iwe ofin ti ọdaran nipinlẹ Ogun, ti ọdun 2006,eyi to wa ni abala 351 ati 421 to si tun ni ijiya ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI