Alaga ajọ eleto idibo lorileede
Naijiria, Ọjọgbọn Yakubu Mahmood ti kede sita pe oludije sipo gomina labẹ asia
ẹgbẹ oṣelu PDP, Bello Matawalle lo jawe olubori nibi eto idibo to kọja lọ.
Ọsan onii Satide ni Ọjọgbọn
Mahmood fidi ẹ mulẹ nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Abuja. Bẹẹ lo
tun sọ pe gbogbo awon oludije patapata ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo tun jawe olubori lawọn ipo oṣelu to ku kaakiri
ipinlẹ naa.
Mahmood jẹ ko di mimọ pe kikede
naa lọ nibamu pẹlu bi ile ẹjọ giga patapata lorileede yi, Supreme Court ṣe paṣẹ
pe ki wọn fagile ẹgbẹ oṣelu APC latari eto idibo abẹle ti wọn ko ṣe e.
O ni ẹgbẹ naa ko ṣe idibo abẹle
rara ko too di pe wọn kopa ninu idibo apapọ laipẹ yi. Eyi lo mu ki wọn fagile
gbogbo ibo APC nipinlẹ naa.
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo awọn oludije patapata lẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Zamfara ni wọn ti n kọrin ọpẹ kaakiri ipinle naa.
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo awọn oludije patapata lẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Zamfara ni wọn ti n kọrin ọpẹ kaakiri ipinle naa.
No comments:
Post a Comment