Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọlọwọ, inu idunnu nla ati
ayọ ni idile Ọba ilẹ Gẹẹsi wa bayii, latari bi iyawo ọmọ ẹ, Meghan Merkel ṣe bi
ọmọ ọkunrin lanti-lanti.
Ko pẹ pupọ ti wọn ni Meghan bẹrẹ si rọbi lati akọbi
ọmọ fun Ọmọọba Harry.
Ori ẹka ayelujara wọn, iyẹn Instagram ni wọn ti kede
iroyin naa pe ki gbogbo aye bawọn yọ fun ti oriire tuntun to ṣokalẹ sinu idile
wọn.
Bakan naa ni wọn tun kede iroyin naa laafin Ọba ilẹ
Gẹẹsi, iyẹn Aafin Buckingham laipẹ yi.
Gẹgẹ bii agbẹnusọ fun aafin ṣe sọ, o fi ye awọn eeyan pe aarọ oni
ti i ṣe Mọnde ni Merghan wọ yara igbẹbi lọ pẹlu ọkọ rẹ, Harry ni ẹgbẹ rẹ.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ
daadaa ninu idile naa, wọn yoo mọ daju pe ọmọ tuntun yi ni yoo jẹ ẹẹkẹjọ ọmọ-ọmọ-ọmọ fun Ọbabinrin ilẹ
Gẹẹsi.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwa ọdun 2018 ni wọn kede pe
arabinrin Meghan ti fẹraku, iyẹn lasiko abẹwo wọn si orilẹede Australia ati New
Zealand.
No comments:
Post a Comment