ỌPẸ O: LẸYIN ỌJỌ MẸWAA, AARẸ BUHARI TI PADA SI NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 6, 2019

ỌPẸ O: LẸYIN ỌJỌ MẸWAA, AARẸ BUHARI TI PADA SI NAIJIRIA

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pada si orilẹede Naijiria lẹyin abẹwo ọlọjọ mẹwaa to ṣe silẹ Gẹẹsi.

Ni bi aago mẹfa kọja ogun iṣẹju ni ọkọ baalu to gbe aarẹ balẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja nirọlẹ ọjọ Aiku Sande ana an.

Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹrin to lọ ni Aarẹ Buhari rinrin ajo lọ si ilẹ Gẹẹsi lẹyin to ṣabẹwo si ilu Maiduguri tii ṣe olu ilu ipinlẹ Bornu.

Ṣaaju abẹwo rẹ si ilu Maiduguri, Aarẹ Buhari kọkọ wa si ipinlẹ Eko nibi ti o ti ṣi awọn akanṣe iṣẹ kan ti ijọba ipinlẹ naa ṣe.

Ẹwẹ, oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adesina sọ oko ọrọ sawọn oniroyin ori ayelujara kan to ni wọn ti n kọroyin pe Aarẹ Buhari lọ gba itọju nilẹ Gẹẹsi ni.

Ọgbẹni Adeṣina beere lọwọ wọn bo ya wọn o tọrọ aforiji lọwọ Aarẹ Buhari ati awọn ọmọ orilẹede Naijiria nibayii ti aarẹ ti pada si Naijiria.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI