ỌNỌREBU DAUDA EWENLA GBE ETO AAWẸ RAMADAANI KALẸ, GBOGBO AYE LO PEJU SIBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 18, 2019

ỌNỌREBU DAUDA EWENLA GBE ETO AAWẸ RAMADAANI KALẸ, GBOGBO AYE LO PEJU SIBẸ

Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi lawọn eeyan kaakiri orileede Naijiria, paapaa ipinlẹ Ekoo ṣi n kan saara si ọkan pataki lara awọn to n ṣe iranlọwọ fawọn alaini lorileede yi, Ọnọrebu Adedipẹ Dauda Ewenla, to jẹ alaṣẹ ati oludari ajọ iranlọwọ nni, Adedas Foundation.

Gbogbo agbegbe Abule Ẹgba, nipinlẹ Eko lo kun fọnfọn lati aarọ ana Fraide, titi di aago mẹsan alẹ nibi idanilẹkọọ Ramadaani ti Ọnọrebu naa ṣagbatẹru ẹ lati fi gbe orukọ Ọlọhun Allah larugẹ.

Gẹgẹ bi eto naa ṣe lọ, ko din ni aadọta lawọn akẹkọọ ile keu ti wọn tun ṣe ayẹyẹ wolimọ fun, pẹlu bi ọkan lara awọn agba ẹlẹsin naa, to tun jẹ gbajugbaja awọn to n ṣe waasi kaakiri agbaye, Alaaji Uthman Ṣannu, Sheu Mufairu Agba Ilọrin ti ṣe waasi.
AWIKONKO gbọ pe eto ayẹyẹ idanilẹkọọ Tamadaani tọdun yi ni wọn pe ni Idanwo ton sọ awọn idi ta a ko fi gbọdọ jẹ ki ohunkohun ba iwa ọmọluabi wa jẹ ati ibẹru Alaah (Temptation, which he emphasized on the reasons why we should not allow anything to tarnish our good character and always have fear of Allah.)

Ọpọ awọn olorin Islam bii Alaaja Mistura Temini Success, Alaaji Mutiu Ọlanrewaju atawọn min in ni wọn forin dawọn eeyan laraya lọjọ naa.

Nigba to n sọrọ, Ọnọrebu Dauda Ewenla to tun jẹ Ọmọba sọ pe kii ṣe akọkọ re e, ati pe ki i ṣe ọna lati wa ojurere awọn eeyan fun ipo oṣelu loun ṣe e fun nitori pe oun ti bẹrẹ ajọ iranlọwọ koun too darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu rara.

O wa a rawọ ẹbẹ sawọn to ti ri jajẹ daadaa, pe kawọn naa dide iranlọwọ fawọn alaini, paapaa awọn ti ko niṣẹ lọwọ nitori pe anfaani nla lo wa ninu keeyan maa ran awọn alaini lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI