Ko too to ana lawọn eeyan ti n
foju sọnọ fun ọjọ onii lati ki ọkan lara awọn gbajumọ sọrọsọrọ ati oniroyin to
ṣẹṣẹ n dide bọ nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Oluwaṣẹgun Pẹlumi Ọkẹowo.
Yatọ si pe Ṣẹgun Ọkẹowo jẹ pedepede ati oniroyin, bẹẹ lo tun fẹran lati maa lu ilu, tẹ gita (Guilter), gba bọọlu, eyi gan lo jẹ ko yan ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona laayo.
Onii tii ṣe ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu
karun ni Ọlọrun tun fi ọdun kan kun ọdun ọdọmọkunrin to n kọ iṣẹ pedepede lọdọ
Ọmọba Babatunde Okunade.
Ọkan lara awọn oniroyin fun
ileeṣẹ wa, AWIKONKO MEDIA CHANNEL ni Ṣẹgun Ọkẹowo, eyi la fi n fi ẹmi imoore
han sii lonii to jẹ ayajọ ọjọ ibi ẹ.
Ẹ ba wa fi adura ranṣẹ sii.
Oriki Ṣẹgun Ọkẹowo
Oriki akọkọ
Itoku Ereke Ọja
Ọmọ A-f’ile p’ogun
Ọmọ Alugbede
gbede b’ọtẹ ja
Ogun o ni ja ja ko
ja ile Itoku
Ọmọ afiju ilẹ Ijẹbu
Ọmọ to n f’oko rẹ jẹ Apena
Ọmọ Ẹgba Onigbedu Ajina
Ọmọ Ẹgba Onigbedu Aji lọwọlọ
Oriki Keji
Ọmọ ara Ake
m’ajo meji
Ọmọ ajogbẹru ma jo gb’ẹkọ
Ọmọ ẹru ni n sin nni, ẹkọ kii si ni’yan
Ọmọ abilake igangan
Ọmọ eluku ṣawo lolo
Ọmọ ologbedu bariba
Iyi wọn n fawo ṣẹri toun akete ati ẹrin
Ọmọ bo le p’ẹja, ko p’ẹja
Ọmọ bo le p’arọgidigba ko p’arọgidigba
Mo pa igangan olodo afara dudu
wowo
Ọmọ abilake ko njẹ igangan
Ọmọ oloke mẹrindinlogun
Ọmọ eleere mẹfa
Ọmọ ṣubu l’ade
Ọmọ agbade l’ọba lori
Ọmọ aroṣẹ f’Ọba jẹ
Ọmọ lakeesi
Ọmọ ọsan la n binu
Ọmọ oru la a ṣe’ka
Ika ti a ba ṣe l’ọsan ko gbe’ni
Lakeesi Ọmọ a'oriṣa l’ofin
Ki a ma gbohun agogo
Ọmọ Ọba laganran
Ọmọ ọlọti ido, Ọmọ ajirọtutu
Ọba ni wọn n jẹ nile Alake majo
Ọmọ jẹun tan, o f’awo
Ọmọ ta tan o f’ọja
Ọmọ kọja o bẹ’gi dina
Ogbe o m’ẹni o ko o
No comments:
Post a Comment